Monisọla Saka, Eko
Ọmọkunrin kan to maa n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, Peter Albert, ti ku lojiji ni kete to ṣe etutu oogun owo tan ni ijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin.
Ọmọkunrin yii ti wa lẹnu iṣẹ ‘Yahoo Yahoo’ yii tipẹ, ṣugbọn o jọ pe bo ṣe n ṣiṣẹ naa to, ko ri owo to jọju nibẹ bii tawọn ọrẹ rẹ, eyi lo mu ko pe ọkan ninu awọn ọrẹ rẹ, David, to si bẹ ẹ pe ko fi ọna han oun, oun naa fẹ ki owo nla maa wọle fun oun nidii iṣẹ ‘yahoo’ ti oun n ṣe yii. Iyẹn mu un lọ sọdọ babalawo kan, oogun ti babalawo naa fun ọmọkunrin yii lo pada ran an sọrun.
Ajalu nla ati kayeefi ni iku ọmọkunrin ti ko ju ogun ọdun lọ to n wa owo, ọrọ ati awọn ohun meremere, ṣugbọn ti ko mọ bo o ṣe le ri i yii njẹ fun gbogbo eeyan.
Ọrẹ Peter toun naa jẹ ẹni ọdun mejidinlogun lo mu un lọ sọdọ Aafaa Araokanmi fun oogun owo ṣiṣe, eyi to pada wa da ẹmi rẹ legbodo dipo ki o sọ ọ di olowo laarin iṣẹju kan gẹgẹ bi aafaa naa ṣe fi i lọkan balẹ.
ALAROYE gbọ pe ọdọ baba rẹ ni Albert n gbe ni agbegbe Asore, ni Atan, nigba ti David n gbe pẹlu awọn obi rẹ ni Iju, awọn adugbo mejeeji naa wa ni ijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, ti jọ jẹ ọrẹ fun igba pipẹ, ṣọọṣi kan naa ni wọn si jọ n lọ.
Nigba ti airiṣe nidii iṣẹ Yahoo rẹ yii ba a ninu jẹ de gongo, Albert beere fun iranlọwọ David ki ohun naa le di ẹni nla nidii gbaju-ẹ ori ayelujara.
David ni airiṣe Albert nidii Yahoo yii, ogun aye ni. O waa ṣeleri pe oun yoo mu un lọ sọdọ baba kan ti oun n lo, iyẹn Araokanmi, o ni baba yii lo ṣe e ti oun fi n ri ṣe nidii ‘yahoo’.
Ni David ba mu Albert lọ sọdọ Araokanmi, ẹni ti wọn tun n pe ni aafaa wa, ni agbegbe Iju, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta.
Ori ẹrọ Wasaapu(Whatsapp) ni wọn ti kọkọ n sọrọ ki ọmọ ọhun too wa Aafaa Araokanmi lọ fun etutu oogun owo to ṣokunfa iku rẹ.”
Araokanmi sọ fun oloogbe pe yoo jẹ awọn asejẹ kan, yoo si wẹ agbo ni ọganjọ oru fun awọn ọjọ kan, lẹyin eyi, ko maa reti Alujannu ti yoo maa gbe owo to to miliọnu marun-un Naira wa fun un lojoojumọ.
Albert bẹrẹ si i rinde oru latigba naa lati ṣe bi aafaa ṣe paṣẹ fun un. Baba rẹ ti idaamu ba lo lọọ fẹjọ rẹ sun awọn ẹṣọ alaabo fijilante adugbo wọn.
Ṣugbọn etutu oogun owo naa ko lọ daadaa, nigba to si pada sile ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, ara rẹ ko balẹ, o si n rẹ ẹ lati inu wa.
Ko too di pe o jẹ Ọlọrun nipe, Albert ṣalaye gbogbo nnkan to ṣẹlẹ laarin oun ati Araokanmi fun baba rẹ, to si tun rọ baba rẹ lati yẹ foonu oun wo lati ka itakurọsọ laarin oun ati aafaa lori wasaapu.
Baba Peter lọ sọ fun awọn fijilante adugbo ti wọn n ṣọ agbegbe Iyanu Oluwa, ni Atan, pe ọmọ oun n fi oru wọle, oun o si fara mọ irin oru olojoojumọ ọhun. O waa kilọ fun awọn fijilante ọhun lati ma ṣe jẹ ki ọmọ oun fi oru wọle mọ.
Si iyalẹnu ati ibanujẹ baba rẹ, Albert tun fi oru wọle bii iṣe rẹ ni ọjọ buruku ọhun, nigba ti baba rẹ rọju ṣilẹkun fun un, o n gbọn, ara rẹ ko si lelẹ. O gbiyanju lati ṣalaye fun baba rẹ pe David mu oun lọ si ọdọ Aafaa Araokanmi kan fun oogun owo ti yoo mu ki Alujannu maa gbe miliọnu marun-un Naira wa fun oun lojoojumọ. O ni wọn fun oun ni asejẹ lati jẹ, ati àkànṣe ọṣẹ aṣiri kan lati fi wẹ.
O sọ fun baba rẹ pe ẹri gbogbo ohun ti oun n sọ wa lori wasaapu oun ati Aafaa ọhun. O waa fun baba rẹ ni koodu (nọmba to fi n ṣi foonu rẹ pe ki o ka gbogbo nnkan ti oun ati Aafaa jọ sọ.
Ni kete ti ọmọ naa jẹwọ irinkurin ati awọn nnkan ikọkọ ti o ṣe pẹlu ọkunrin naa lo ku.
Ohun ti awọn kan n sọ ni pe o ṣee ṣe ki wọn tan an si nnkan to ṣe yii, ko si jẹ pe awọn ti wọn mu un mọ Aafaa yii naa ni wọn lo o.