Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Epe nla nla lawọn eeyan n ṣẹ fun ọdaju abiyamọ kan to ju ọmọ oojọ sinu sọkawee lopopona Ọyọ, lagbegbe Olorin, Adiyan, nipinlẹ Ogun, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii.
Ọlọrun to ni ẹmi ọmọ naa i lo lo fi awọn ọmọ keekeeke ti wọn n ṣere nitosi ibẹ ṣe sababi fun un, awọn ni wọn pariwo ọrọ naa sita ti wọn fi ri ẹjẹ ọrun yii yọ laaye ninu sokawee ọhun. Ibi ti wọn ti gbe e jade naa lagbara pupọ, eyi lo fa a to jẹ o ṣi n gba itọju lọsibitu kan lọwọ ba a ṣe n kọ iroyin yii.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ọmọ oojọ lọmọ naa, iwọ inu rẹ ṣi tuntun sibẹ lasiko ti wọn gbe e jade ninu sọkawee ọhun.
ALAROYE gbọ pe aarin meji irin to bo ori sọkawee naa ni ẹni to ju ọmo ikoko yii sibẹ gba ju u sinu ẹ, o si ṣee ṣe ko jẹ oru tabi idaji kutu hai lo ṣiṣẹ ibi ọhun.
Awọn ọmode kan to n ṣere nitosi sọkawee naa ni wọn n gbọ ẹkun ọmọ kekere jojolo lati inu koto ẹgbin ọhun, nigba ti wọn si yọju wo o gẹgẹ bii ọmọde, ohun ti wọn ri ko ye wọn, ni ọkan ninu wọn ba lọọ sọ fun mama kan pe adiyẹ ti ja bọ sinu sọkawee, o n dun lati ibẹ jade.
Mama naa lo waa ri i pe eeyan lo wa ninu sọkawee, ẹkun ọmọ lo n ti ibẹ wa, ki i ṣe ti adiẹ rara, nigba naa lo kegbajare sawọn eeyan to wa nitosi, bi wọn ṣe bẹrẹ eto lati yọ ọmọ naa jade niyẹn.
Wẹda kan ni wọn lọọ pe to ba wọn ge irin oju sọkawee naa kuro, bi wọn ṣe gbe ọmọ naa jade tẹgbin-tẹgbin niyẹn. Igba ti wọn gbe e jade ni wọn ri i pe ọmọ ọkunrin lantilanti ni, iwọ inu rẹ to wa nibẹ ṣi tuntun sibẹ, eyi to fi han pe ọmọ naa ko ti i ju ọmọ ọjọ kan ṣoṣo lọ.
Nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ni wọn gbe ọmọ naa jade lọjọ yii, ẹsẹkẹsẹ naa ni wọn ti fi to awọn ọlọpaa teṣan Agbado leti, ti DPO Kuranga Yero atawọn ikọ rẹ si debẹ, bẹẹ naa ni wọn sọ fun alaga ibilẹ atawọn yooku to yẹ ko gbọ, won si gbe ọmọ ọhun lọ sọsibitu fun itọju to peye.
Ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe ọmọ naa ni ohun rere ti yoo ṣe laye ni, pẹlu bo ṣe jẹ pe o ti pẹ ninu igbọnsẹ to bẹẹ ti ko si ku, to jẹ wọn ri i gbe jade lai si iyọnu ni.