Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan mẹta ni wọn ku, nigba tawọn mi-in si tun fara pa yannayanna latari ijamba ọkọ to waye nigboro Akurẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin yii.
ALAROYE gbọ pe ọmọ Yahoo kan ni wọn lo wa ọkọ ayọkẹlẹ Toyota rẹ ni iwakuwa lagbegbe Ijọ Mimọ, Ijọka, niluu Akurẹ, to si ṣe bẹẹ lọọ kọ lu awọn ọlọkada bii marun-un pẹlu ero ti wọn gbe sẹyin.
Mẹta ninu awọn to kọ lu naa la gbọ pe wọn ku loju–ẹsẹ nigba tawọn yooku ti wọn fara pa ṣi wa lẹsẹ–kan–aye ẹsẹ–kan–ọrun nileewosan ti wọn ko wọn lọ fun itọju.
Wọn ni ọmọ Yahoo to wa ọkọ yii kọkọ gbiyanju lati sa lọ ni kete ti iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn niṣe lawọn eeyan gba ya a, ti wọn si mu un. Pẹlu ikanra ni wọn fi ja a sihooho, ti wọn si lu u lalubami. Bi wọn ṣe n juko lu u ni wọn n la igi ati ohun ti ọwọ onikaluku ba mọ ọn, bẹẹ ni wọn n ta a nipaa. Gbogbo bo ṣe n gbiyanju lati sa ninu fidio kan to tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn n lu u. Awọn ọdọ to wa nitosi si lu u titi ti ẹmi fi bọ lara oun naa, ni wọn ba fi oku rẹ silẹ nibi to na gbalaja si, onikaluku si ba tirẹ lọ, nitori ibẹru awọn ọlọpaa.
Bakan naa ni wọn dana sun mọto to fi paayan naa.
Awọn alaaanu kan gbiyanju lati gbe awọn to fara pa lọ si ọsibitu to wa nitosi, ti oku awọn to ba iṣẹlẹ ọhun rin si wa nilẹ ibi ti ọkọ tẹ wọn pa si lasiko ta a si n ko iroyin yii jọ lọwọ.