Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ siluu Odigbo, ti ni ki akẹkọọ kan ti ko ti i ju bi ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lọ, Ọmọlayọ Olowoniyi ṣi lọọ maa ka iwe rẹ ninu ọgba ẹwọn to wa l’Okitipupa, lori bi wọn ṣe loun atawọn ẹgbẹ rẹ kan lu awọn tiṣa mẹrin lalubami, ti wọn si tun ṣe wọn leṣe.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni abule kan ti wọn n pe ni Alagbado, nijọba ibilẹ Odigbo.
Gẹgẹ bii ẹsun ti ọlọpaa agbefọba, Usifo James, ka si ọmọkunrin ọhun lẹsẹ, o ni ṣe ni olujẹjọ ọhun atawọn ẹgbẹ rẹ kan ti awọn agbofinro ṣi n wa dira pẹlu awọn nnkan ija oloro bii igo, igi ati ada, ti wọn si lọọ ṣe akọlu si awọn olukọ mẹrin to wa nileewe girama, Our Saviousr Comprehensive College, Alagbado.
Awọn olukọ mẹrẹẹrin ọhun ni: Ọlafusi Ọlamipọsi, Ọlabisi Michael, Akintoye Ọlajide ati Abiwo Ọlatunde, ti wọn wa lati ile-ẹkọ olukọni agba Adeyẹmi, to wa niluu Ondo, ti wọn si waa ṣe eto kọmọ-n-wo-ọ nileewe naa.
Usifo ni ẹsun mejeeji ti wọn fi kan olujẹjọ ta ko abala okoolelẹẹẹdẹgbẹta din mẹrin (516) ati ọrinlelọọọdunrun le mẹta (383) iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Agbefọba ọhun tọrọ aaye pe ki wọn sun igbẹjọ siwaju diẹ, koun le lanfaani lati ṣe ayẹwo si iwe ipẹjọ to wa lọwọ oun, bẹẹ lo ta ko ẹbẹ agbẹjọro olujẹjọ, Amofin V. A. Akinfẹ, lori ọrọ gbigba beeli onibaara rẹ.
O ni o ṣee ṣe ki Omọlayọ ṣi anfaani beeli ti wọn ba fun un lo, ko ma sí yọju sile-ẹjọ mọ nigba ti igbẹjọ ba bẹrẹ.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ D. O. Ogunfuyi pasẹ ki akẹkọọ ọhun ṣi lọọ maa ṣere lọgba ẹwọn Okitipupa, titi dọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ẹsun ti wọn fi kan an.