Faith Adebọla
Owọ awọn agbofinro ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ba afurasi ọdaran kan, Akinyọde Rasaq, fun ẹsun ifipa-bani-lopọ, ọmọọdun mẹrinla kan ti a ko fẹẹ darukọ ẹ ni gende yii ki mọlẹ nigba tiyẹn n kiri mọin-mọin laduugbo wọn, lo ba wọ wọ yara ẹ, o si ṣọmọ ọhun yankanyankan. Lẹyin to tẹ ara ẹ lọrun daadaa tan lo taari ọmọ ọhun sita, ko too di pe aṣiri rẹ tu.
ALAROYE gbọ pe agbegbe kan ti wọn n pe ni Bode Olude, nigboro ilu Abẹokuta, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun, niṣẹlẹ yii ti waye.
Nnkan bii aago mẹwaa owurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2024, ni ọmọbinrin taa n sọrọ rẹ yii kiri mọin-mọin, ko si ṣẹṣẹ maa kiri, awọn onibaara rẹ ti mọ ọn mọ bo ṣe n ṣọrọ aje fun mama ẹ to gbe igba mọin-mọin le e lori.
Wọn ni b’ọmọbinrin yii ṣe sọrọ aje de adugbo ti Rasaq wa lo pe e pe ko waa ta mọin-mọin foun, o si daju pe inu ọmọ naa yoo ti kọkọ dun pe aje bugba oun jẹ laaarọ ọjọ ọhun, tori mọin-mọin ẹgbẹrun kan Naira (N1,000) lo ra tan lẹẹkan. Amọ ibi ti ọrọ naa mu ifura dani si ni bi onibaara yii ṣe sọ pe oun ko ni i sanwo, afi toun ba kọkọ jẹ mọin-mọin tan.
Gẹgẹ bi ọlọpaa kan ti ko fẹẹ darukọ ara ẹ ṣe sọ fun akọroyin Punch, o ni: “Ọkunrin yii sọ f’ọmọ oni-mọin-mọin pe ko mu suuru foun, toun ba jẹun tan loun maa fun un lowo, igba to si jẹun ọhun tan, ko sanwo. Ibi t’ọmọ ti n reti owo ni gbogbo aago ti lọ, ibẹ lọsan-an ti pọn ba wọn. Nnkan bii aago kan ọsan lu, ko si fi bẹẹ seeyan nitosi, lafurasi yii ba tan ọmọbinrin ọhun wọ yara ẹ, o si fipa ba a laṣepọ. Igba to ṣetan lo too yọnda ẹ.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, naa ti jẹrii sọrọ yii, o ni, “Awọn ọlọpaa ẹka ti Bode Olude ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn ri gbogbo ayika ati ẹri to wa nibẹ, wọn si ti fi pampẹ ofin mu afurasi naa, o ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lolu-ileeṣẹ wa, l’Eleweẹran, nibi ti wọn ti n ṣewadii ijinlẹ lọwọ.
“Bakan naa la ti gbe ọmọbinrin yii lọ sọdọ awọn oniṣegun, ayẹwo si ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni ibalopọ tipa-tikuuku kan waye loju ara ọmọ ọhun, wọn lẹnikan ti fagidi wọle si i lara.”
Alukoro ni lẹyin iwadii, gbogbo alaye yooku di kootu, niwaju adajọ.