Ọmọọdun mẹtala ti Ayọbami n ṣe lẹsinni fun lo fipa ṣe ‘kinni’ fun l’Agọ-Iwoye

Gbenga Amos, Abeokuta

Afaimọ ki ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn yii, Ayọbami Oluwatobilọba Runsewe, ma ti maa ge’ka abamọ jẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn abamọ ki i ṣaaju ọrọ, majeṣin ọmọọdun mẹtala pere ti wọn ni ko maa kọ ni lẹsinni lo ki mọlẹ, o si fipa ba a laṣepọ.
Ohun ta a gbọ ni pe iṣẹ tiṣa ni wọn gba afurasi ọdaran naa fun, nileewe aladaani ti wọn ti n kọ awọn ọmọ nọsiri ati pamari, l’Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun.
Wọn ni ọkan lara awọn ọmọ kilaasi ti Ayọbami n kọ niwee lọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun, tawọn ọmọ naa ba ti pari ẹkọ lojumọmọ, wọn tun maa n duro ṣe lẹsinni di aago mẹrin aabọ irọlẹ.
Wọn ni niṣe ni wọn pari lẹsinni tan lọjọ kan, Ayọbami dọgbọn tan ọmọdebinrin naa lọ sile ẹ laduugbo Ayegbami, l’Agọ-Iwoye, bii ere bii awada, o fipa ba ọmọ naa sun.
Mama ọmọ ọhun lo lọọ fẹjọ ọdaran tiṣa yii sun ni tọlọpaa, o mu ọmọbinrin naa dani, ọmọ naa si fẹnu ara ẹ sọ nnkan to ṣẹlẹ ati bo ṣe ṣẹlẹ, mama naa tun fi pata tọmọ ẹ wọ lọjọ tiṣẹlẹ ọhun waye han, pẹlu bi ẹjẹ ṣe yi pata ọhun balabala latari ibalopọ tulaasi naa.
DPO teṣan ọhun, SP Noah Adekanye ṣeto pe kawọn ọmọọṣẹ lọọ mu Ayọbami, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un yii, lọwọ ba jagunlabi, lo ba dero ahamọ wọn.
Nigba ti wọn bi i leere bọrọ ṣe jẹ, o kọkọ loun o mọ nipa ẹ, ṣugbọn nigba tọmọbinrin naa ko o loju, ṣe boju ba koju, ẹnu aa ri dẹẹrẹ-dẹẹrẹ, wọn niṣe ni kẹkẹ pa mọ atioro tiṣa lẹnu, ọrọ pesi jẹ, lo ba n wo pako bii ole tilẹ mọ ba.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ ki wọn fi Abayọmi ṣọwọ si ẹka to n gbogun ti ṣiṣe ọmọde baṣubaṣu, fun iwadii to lọọrin.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, to fiṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe, afurasi naa maa kawọ pọnyin rojọ ni kootu laipẹ.

Leave a Reply