Oni POS l’Abubakar fẹẹ lu ni jibiti tọwọ fi tẹ ẹ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to lọ yii, ni ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, mu ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Muhammed Abubakar, to si n ṣẹju pako lakolo wọn fẹsun pe o fẹ lu oniṣowo POS kan ati ileepo ni jibiti ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ileepo kan ni agbegbe Amọyọ, niluu Ilọrin, lọwọ ti tẹ Abubakar lẹyin to ra epo tan, to tun ni ki Abdulraheem Nafisat to n ta epo tun fi ẹgbẹrun lọna aadọta naira ṣọwọ sinu asunwọn oun, to si ni oun yoo fi owo naa le e lọwọ ati owo nnkan miiran to ra. Ṣugbọn ṣe ni afurasi naa fẹẹ fẹsẹ fẹ ẹ, lai san owo-epo ati ẹgbẹrun lọna aadọta naira ti Nafisat fi sọwọ si akanti rẹ, eyi to mu ki wọn pariwo le e lori, ti ọwọ ajọ NSCDC si tẹ ẹ.

Ni akoko ti ajọ naa n ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun afurasi ọhun lo jẹwọ pe oun ti n ṣe iṣẹ jibiti lilu ọjọ ti pẹ. O ni oun maa n lọọ lu awọn eeyan ni jibiti lawọn otẹẹli ati awọn ileetaja igbalode nla niluu Ilọrin ati agbegbe rẹ. Adari ajọ ẹsọ alaabo naa, Iskilu Ayinla Makinde, ti waa paṣẹ pe ki wọn ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si foju afurasi ọhun ba ile-ẹjọ lai fi akoko sofo.

 

Leave a Reply