Faith Adebọla, Eko
Ọba Ẹnitan Adeyẹyẹ Ogunwusi, Ọọni ti Ile-Ifẹ, ti sọ pe ko sohun ti Yoruba le ṣe si i, ti wọn ba fẹ ki erongba wọn nipa didaduro, didi orileede kan, wa si imuṣẹ, afi ki awọn obinrin gbaruku ti wọn, ki wọn si ṣatilẹyin fun igbesẹ bẹẹ lo fi le yọri si rere.
Ọsan Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni Ọọniriṣa sọrọ ọhun laafin rẹ niluu Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, nigba ti Alana ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye lewaju awọn obinrin to to ẹgbẹrun kan (1,000), ti wọn n ṣe ẹgbẹ Obinrin Oodua Agbaye lọọ ṣe ‘ẹ n lẹ bẹ’un’ si ọba alaye naa, ti ọba naa si wure fun wọn. Alukoro ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọgbẹni Maxwel Adelẹyẹ, ni lati orileede to ju mẹtadinlogoji kari aye lawọn obinrin naa ti waa dara pọ mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn ni Naijiria fun eto ijijagbara ọhun.
Alaga ẹgbẹ awọn obinrin Oodua ọhun, Ọmọọba-binrin Simisade Kuku-Ọnayẹmi sọ pe awọn irunmọlẹ ilẹ Yoruba lo ta awọn nidii lati gbe igbesẹ iṣẹṣe to maa le mu ki erongba bi Yoruba yoo ṣe da duro lai si itajẹsilẹ ṣee ṣe.
O ni: “Gbogbo wa tẹ ẹ n wo lonii yii, ọjafafa akọṣẹmọṣẹ laaye kaluku wa ni wa. Dokita wa laarin wa, amofin, agbẹjọro, ẹnjinnia, oluṣiro owo, oniroyin, oṣiṣẹ banki, olukọ fasiti, oniṣowo, lọgaa-lọgaa lẹnu iṣẹ ọba wa laarin wa, gbogbo wa la si nifọn leeekanna laaye ara wa, ṣugbọn inu wa o dun si bi nnkan ṣe ri nilẹ baba wa, idi niyi ta a fi gbera lati waa ṣeto ọna abayọ nilana ti iṣẹṣẹ.”
Ninu ọrọ rẹ, Ọọni ni ero to lodi ni lati fọwọ rọ awọn obinrin sẹyin nidii ogun ati ijijagbara. “Awọn obinrin ki i ṣe ojo, wọn ki i ṣe ọlẹ, akinkanju gidi ni wọn. Latinu Bibeli, a ka nipa bi obinrin ti wọn pe ni Deborah ṣe jagun fawọn eeyan rẹ, to si jagunmolu.
“Laye ode oni, ọpọ obinrin lo ti fakọyọ, ti wọn si huwa akin, ti wọn ṣaaju oogun, ti wọn si ṣẹgun pẹlu. Ọkan ni Mọremi, o jagun lati gba awọn eeyan Ifẹ iṣẹmbaye silẹ kuro lọwọ awọn ara Igbomẹkun ti wọn buru jọjọ, ti wọn si jẹ ọta wa, sibẹ, Mọremi ṣaaju ogun, o si ri i ṣe.
“Tori naa, gbogbo igbesẹ ijijagbara ati bi Yoruba ṣe fẹẹ da duro ko ṣee ṣe lẹyin ẹyin obinrin o, afi ko ni atilẹyin wọn ninu, afi ka jẹ ki wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ, ka si fi tiwọn ṣe.
“Ẹ jẹ ki n la a mọlẹ pe lai fi tawọn obinrin ṣe, Yoruba o le debikan pẹẹ.
“Mo ki yin kaabọ si orirun Yoruba o, mo si gbadura k’Ọlọrun ṣe irinajo yin ni rere.”