Aderounmu Kazeem
Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, atawọn ọba alaye mi-in ti wọn jẹ aṣoju kaakiri ilẹ Naijiria wa niluu Abuja bayii o. Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn wa lọ fun ipade pataki kan.
ALAROYE gbọ pe Sultan Sokoto, Ọba Sa’ad Abubakar, lo ko awọn ọba alaye ọhun sodi lọọ ba Buhari ṣepade.
Koko ohun ti wọn fi pe ipade ọhun ṣi wa ni bonkẹle, nitori wọn ko ti i fi sita fẹnikẹni. Lara awọn ọba to wa nibẹ ni Ọba awọn Tapa, iyen Etsu Nupe, alaga awọn lọbalọba nipinlẹ Imo, nilẹ Ibo lọhun-un atawọn mi-in.