Kazeem Aderohunmu
Aṣaalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lawọn olorin Musulumi bẹrẹ si i pin iroyin ọhun laarin ara wọn pe Ọlọrun ti ṣe e, awọn janduku ajinigbe Fulani ti tu Basit ọmọ Damilọla olorin silẹ.
Ọgbọn miliọnu naira ni wọn ni ki ọkunrin olorin yii lọọ mu wa ni kete ti wọn ti pe e lẹyin bii wakati meloo kan ti ọmọ ẹ ti ko ju ẹni ọdun mẹtalelogun lọ ti wa lahaamọ wọn.
Ni gbogbo ọsan ana lawọn olorin ẹgbẹ ẹ ṣi ṣe fidio kan ti wọn fi n bẹbẹ pe ki awọn ajinigbe yii ṣaanu ọkunrin naa nitori owo ti wọn n beere fun yẹn ti pọ ju.
Aṣaalẹ ana ni iroyin mi-in gba igboro pe wọn ti tu u silẹ, lẹyin ti wọn gba owo lọwọ awọn obi ẹ, ti Abdul-Basit, ọmọ Poli Kwara, si ti wa nile bayii.
Ninu ọrọ ti Damilọla, ba ALAROYE sọ, o ni awọn ajinigbe ọhun gba owo to pọ ki wọn too le tu ọmọ oun silẹ, bẹẹ lo fi kun un pe awọn ti sin iyawo aburo oun tawọn eeyan buruku yii pa lasiko ikọlu ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, opin ọsẹ to kọja yii ni wọn kọ lu mọlẹbi Damilọla olorin Islam tawọn eeyan tun mọ si Ẹsin-o-gba-mi-laye, ile aburo ẹ to wa ni Gaa Saka ni wọn sọ pe awọn Fulani kan wọ lọ, wọn pa iyawo aburọ ẹ to wa ninu oyun, bẹẹ ni wọn ji Basit, ọmọ ẹ to n gbe pẹlu wọn lọ.
Olohun a saanu wa.