Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ariwo ijo ati ayọ lo sọ ni aafin Adimula, niluu Ileefẹ, nigba ti iroyin ayọ kan wọn pe Olori Ọọni Ileefẹ, Silẹkunọla Ogunwusi, bi ọmọkunrin ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ori ikanni Instagraamu, ọọniadimulaifẹ, to jẹ ti Ọọni Ileefẹ ni wọn ti kede iroyin ayọ naa pe ‘‘Gbogbo mọlẹbi ile Oduduwa ati Olori Silẹkunọla ku oriire ọmọkunrin, ọmọọba ti wọn bi lonii sori itẹ Oduduwa.
Iya ati ọmọ wa daadaa fun ogo Ọlọrun.
Latigba ti iroyin ayọ naa ti gbalẹ kan ni awọn eeyan ti n ki Kabiyesi, Ọọni Ileefẹ ku oriire.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni awọn kan n gbe e kiri pe Olori naa ti bimọ, ṣugbọn ti awọn to wa laafin Kabiyesi sọ fun akọroyin wa pe ko si ohun to jọ bẹẹ, ko too di pe Olori naa bimọ lonii.
ALAROYE pe amugbalẹgbẹẹ Ọọni lori eto iroyin, Moses Ọlafare, ṣugbọn ko gbe ipe wa. Ṣugbọn awọn to mọ bo ṣe n lọ laafin fidi iroyin ayọ yii mulẹ fun akọroyin wa.