Agọ ọlọpaa to wa ni Panti, nipinlẹ Eko, ni igbẹjọ ti waye lori awọn ti wọn mu pe wọn fẹẹ ṣewọde ni Togeeti-Lẹkki, nipinlẹ Eko. Ninu awọn ti wọn mu yii ni oṣere ilẹ wa, Debo Adedayọ ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni atawọn ọdọ mi-in bii wa.
Lẹyin ti ile-ejọ alagbeeka kan ti jokoo, ti wọn si fẹsun kan awọn eeyan naa pe wọn dalu ru ni awọn eeyan naa nipasẹ agbẹjọro wọn sọ pe awọn ko jẹbi.
Eyi lo mu ki ile-ẹjọ naa gba oniduuro ẹnikọọkan wọn pelu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro kọọkan ni iye kan naa.
Bẹẹ ni wọn ni ki wọn lọọ ṣe ayẹwo Korona, ki wọn si mu iwe ẹri rẹ wa.
Inu oṣu kẹta, ọdun yii ni wọn sun igbẹjọ mi-in si.