Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Agbe kan ti awọn ajinigbe ji gbe ni Iyemero-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, Alaaji Jimoh Olodan, ti gba iyọnda lọwọ awọn ajinigbe naa.
Agbẹ yii ni wọn sọ pe awọn ọdẹ ibilẹ, ẹṣọ Amọtẹkun ati awọn ẹṣọ alaabo miiran ri ni agogo marun-un aabọ idaji ọjọ Aje, Mọnde, ninu igbo kan ni agbegbe ilu Patigi, nipinlẹ Kwara.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii ni wọn ji ọkunrin naa ninu oko rẹ ni Eleguro, lagbegbe Iyemero-Ekiti, nigba ti awọn agbebọn ti ko din ni mejidinlogun ya wọ oko rẹ, ti wọn si gbe e lọ.
Awọn ajinigbe naa pe awọn mọlẹbi rẹ ni ọjọ Aiku, Sannde, ti wọn si sọ pe ki wọn lọọ mu ọgbọn miliọnu naira wa, ki wọn too le tu u silẹ.
Mọlẹbi ọkunrin agbẹ ti ko fẹ ki wọn darukọ oun yii sọ fun ALAROYE ni ọsan ọjọ Aje, Mọnde, pe wọn ti tu agbẹ naa silẹ, lẹyin ti awọn ọdẹ atawọn fijilante ati awọn ọmọ ẹgbẹ OPC fọn sinu igbo.
O fi kun un pe awọn mọlẹbi ti kọkọ san miliọnu meji ki wọn too tu ọkunrin naa silẹ.
“Awa mọlẹbi ti san miliọnu meji ni ọjọ Sannde pẹlu adehun pe a maa san owo to ku. Ṣugbọn awọn ọdẹ to wa ninu igbo bẹrẹ si i yinbọn kikan kikan lati owurọ ọjọ Sannde titi di oru ninu igbo, ti wọn si ti fẹẹ jade si ipinlẹ Kogi ati Kwara.
“Bi awọn ajinigbe yii ṣe ri i pe wọn ti sun mọ ọdọ awọn, ti wọn si n gbọ iro ibọn kikan, ni wọn sare fi ọkunrin agbẹ yii silẹ, ti wọn si fi ere gee. A dupẹ lọwọ Ọlọrun, pe gaga ni ara ọkunrin agbẹ yii ya.”
Nigba ti ALAROYE ba Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọrọ, o sọ pe awọn ọlọpaa lo gba agbẹ naa silẹ lọwọ awọn ajinigbe naa.
“Ṣebi mo sọ fun ẹ, ni ọjọ ti wọn ti ji ọkunrin agbẹ yii gbe pe awọn ọlọpaa yoo ṣe iṣẹ takuntakun lati gba a jade.
“Awa ọlọpaa la ṣaaju wọn ni wọn ṣe da gbogbo igbo to wa ni agbegbe naa ru, ti awọn ajinigbe naa si sare fi agbẹ naa silẹ. Ṣugbọn ọlọpaa ko gbọ nipa miliọnu meji ti awọn mọlẹbi naa sọ pe awọn san.”