Wọn ni Emir Ilọrin fẹẹ fọba Hausa jẹ ni Jẹbba, ni Kabiyesi ba ni wahala lo n fa lẹsẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Kabiyesi ilu Jẹbba, HRM Alhaji Abdulkadir Alabi Adebara, ti ṣe ikilọ pe ki Emir Ilọrin, Alhaji Ibrahim Zulu Gambari, yi ipinnu rẹ pada lori fifi Mallam Nasiru joye Sarki Sugaba Hausawan ni Jẹbba, to ba a dan an wo pẹrẹn, wahala yoo sẹlẹ niluu Jẹba.

Kabiyesi ilu Jẹba sọ fun alaroye pe, Emir ilu Ilọrin ti mu Ọjọ keji Osu Keje gẹgẹ bii Ọjọ ti yoo jawe oye fun Mallam Nasiru gẹgẹ bii Sarki Sugaba Hausawan tí ilu Jẹba, ti o tumọ si Ọba Jẹbba ni ede Yoruba, to si lodi si ero ara ilu Jẹbba tori pe wọn ti ni ọba tẹlẹ.

Adebara tẹsiwaju pe oye Sarki Fulani wa ni ilu Jẹbba lọwọlọwọ bayii to si jẹ pe Ọba Jẹbba lo yan an loye, sugbọn o jẹ iyalẹnu pe Emir Ilọrin fẹẹ fi Hausa jọba ni Jẹbba lẹyin ti Yoruba ti n jọba bọ lọjọ pipẹ ati pe Emir ti n gbinyanju lọjọ pipẹ lati dabaru Ọba Yoruba ni Jẹbba, eyi lo sokunfa to fi ni ọba Jẹbba ko gbọdọ lọọ kirun raka meji ni Yidi mọ, lakooko ayẹyẹ ọdun Musulumi.

Kabiyesi fi kun ọrọ rẹ pe, oun o mọ ibi ti Nasiru ti fẹẹ jogun oye ti wọn fẹẹ fi i jẹ yii, tori pe wọn ki i joye ninu iran wọn, bi yoo ba si jẹ oye, Ọba Jẹbba nikan lo laṣẹ lati fi i jẹ ẹ. O ni ki Emir jawọ kuro lapọn ti ko yọ, ko dami ila kana, to ba dan an wo pẹrẹ, ogun yoo sẹlẹ ni ilu Jẹbba.

Leave a Reply