Inu idunnu nla ni olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Enock Adeboye, ati gbogbo awọn ọmọ ijọ naa wa bayii pẹlu iroyin ayọ ti wọn gbọ pe awọn ajinigbe to gbe awọn ọmọ ijọ naa lọsẹ to kọja nipinlẹ Kaduna ti tu awọn mẹjẹẹjọ ti wọn gbe ọhun silẹ.
Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Pasitọ Adeboye kede iroyin ayọ naa lori ẹrọ abẹyẹfo rẹ. Lori twitter re lo ti sọ pe awọn ajinigbe ti tu awọn ọmọ ijọ naa mẹjọ ti wọn ji gbe loju ọna Kachia-Kafachan, nipinlẹ Kaduna nigba ti wọn n lọ fun eto adura kan silẹ.
Ni kete ti awọn eeyan ọhun gba itusilẹ ni wọn ko wọn lọ si ile iwosan fun itọju.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, lawọn agbebọn naa ji awọn eeyan mẹjọ ọhun gbe lasiko ti wọn n lọ fun eto kan. Aadọta miliọnu ni wọn beere fun nigba ti wọn ji wọn gbe, ṣugbọn a ko ri okodoro pe boya wọn sanwo ti awọn ajibigbe yii beere fun ki wọn too ri itusile, abi wọn kan fi wọn silẹ lasan.