Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Dokita agba lọsibitu Jẹnẹra Imẹkọ-Afọn, Ọladunni Ọdẹtọla, ati nọọsi kan, Abilekọ Bamgboṣe, ti wa lakata awọn ajinigbe bayii. Alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu kẹrin yii, ni awọn kan gbe wọn lọ loju ọna Abẹokuta s’Imẹkọ.
Inu igbo la gbọ pe awọn agbebọn to ji wọn gbe ti jade wa, ni abule kan ti wọn n pe ni Olubọ.
Mọto Camry kan (Muscle) ti nọmba ẹ jẹ KTU 584 FR, ni Dokita Ọdẹtọla ati nọọsi naa wa ninu ẹ ti wọn fi da wọn duro, aarin ọna naa ni mọto ọhun ṣi wa tawọn ọlọpaa fi ri i lẹyin ti awọn ajinigbe ti ko awọn mejeeji wọgbo lọ tan.
A tilẹ gbọ pe wọn jo taya iwaju ọkọ naa, bẹẹ ni wọn lu iho si gilaasi iwaju rẹ pẹlu. Iroyin kan ti a ko fidi ẹ mulẹ, sọ pe kinni kan to fara jọ ibi ti wọn n ki ibọn AK47 si, wa nilẹ ibi ti mọto naa wa.
Iwe idanimọ dokita yii ati akọsilẹ ipade ẹgbẹ awọn dokita ti wọn ṣe ni wọn ba ninu mọto naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
Lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ si i, ALAROYE pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣugbọn ko gbe ipe rẹ. A fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i, ko fesi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹka iroyin kan sọ pe ọkunrin naa ti fidi ẹ mulẹ fawọn. Wọn lo sọ pe awọn ọlọpaa ti n wa awọn ajinigbe naa.