Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi ẹni lu iya iyawo ba ṣe diẹ nile ana, ẹni to waa pa iya iyawo tiẹ nkọ! Iyẹn lọrọ tawọn eeyan n sọ nipa Ọpẹyẹmi Adeọla Ganiyu, ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) to lu iya iyawo ẹ tan, to tun gun un lọbẹ pa nitori iya naa da si ija oun ati iyawo ẹ, nile wọn to wa ni Atan-Ọta, nipinlẹ Ogun.
Ọjọ kẹta, oṣu karun-un yii, ni ọwọ ọlọpaa ba Ganiyu, iyẹn lẹyin to pa iya iyawo ẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Abọsẹde Oyewọle.
ALAROYE gbọ pe Ganiyu Ọpẹyẹmi yii fẹran ko maa lu iyawo ẹ lori awọn ọrọ ti ko to nnkan, lilu gidi to jẹ ko si abiyamọ ti oju rẹ yoo gba iru rẹ ni wọn pe e pẹlu.
Lọjọ ti iya iyawo da si ija wọn yii, iya naa lọ sibẹ lati kilọ fun un pe ko yee lu ọmọ oun ni, nitori wọn ni Ọpẹyẹmi tun lu iyawo ẹ bo ṣe maa n ṣe. Koda, o da apa oriṣiiriṣii si i lara pẹlu lilu naa.
Eyi ni Abọsẹde, iya iyawo Ọpẹyẹmi, gbọ to fi lọ sile ọkọ ọmọ rẹ lati da a lẹkun lilu to n lu obinrin naa.
Ṣugbọn inu bi Ọpẹyẹmi bo ṣe ri iya naa, lo ba mu iya iyawo rẹ naa lu, o lu u tan lo tun fa ọbẹ yọ, o si fi ọbẹ naa gun iya ni egungun iha, nibi ti wahala ti ṣẹlẹ si obinrin naa niyẹn.
Awọn eeyan sare gbe mama lọ sọsibitu fun itọju, ṣugbọn lẹnu itọju naa lo dakẹ si. Bi Ọpẹyẹmi ṣe gbọ pe iya iyawo oun ti ku latọwọ oun lo ti sa lọ, wọn wa a titi ki wọn too ri i mu lọjọ Aje ti i ṣe Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun 2021.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, ni Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni Ganiu sa lọ lẹyin ti iya iyawo ẹ ku, ibẹ ni awọn ọlọpaa ti lọọ mu un.
O fi kun un pe ọmọ ẹgbẹ okunkun to lagbara ni Ọpẹyẹmi nibi ti wọn ti ri i mu.
Oyeyẹmi sọ pe ọkunrin naa wa lara awọn to ko janduku lọ si teṣan ọlọpaa Atan-Ọta loṣu kẹwaa, ọdun to kọja, lasiko iwọde SARS. O ni ọmọ yii pẹlu awọn to pa DPO teṣan naa lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.
Ni bayii, CP Edward Ajogun ti ni ki wọn gbe e lọ si ẹka SCID to n tọpinpin iwa ọdaran, ki wọn wadii siwaju si i nipa Ọpẹyẹmi Adeọla Ganiyu to lu iya iyawo ẹ pa.