Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, sọọbu mọkanla lo jona, ti ọkẹ aimọye miliọnu si segbe ni ọja Alanamu, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, loru mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita, lọjọ Aje. lo ti sọ pe ni nnkan bii aago marun-un idaji ni ijamba ina ọhun waye, ti ṣọọbu mọkanla si jona raurau. O tẹsiwaju pe dukia to jona sun mọ miliọnu mẹwaa, ti ajọ naa si doola dukia to le ni miliọnu mẹjọ lọwọ ina.
Adari ajọ panapana ni Kwara, ỌmọỌba Falade John, ti rọ gbogbo awọn olugbe ilu yii ki wọn maa wa ni oju ni alakan fi n sọri nigba gbogbo lati dena iru iṣẹlẹ bẹẹ, ki wọn si maa pa gbogbo ina nigba ti wọn ba fẹẹ jade nile.