Theo Ọmọlohun, Oke-Ogun
Oluwo ilu Iwo, Ọba Abdulwaheed Adewale Akanbi, Tẹlu kin-in-ni, ti ṣekilọ fawọn oriṣa gbogbo to ba fẹẹ ṣe akọlu si i, o ni wọn yoo jẹ iyan wọn niṣu ni, oun yoo si ri i pe oun lo gbogbo agbara t’Ọlọrun fun oun lati doju ija kọ wọn, toun yoo si lu wọn lalubolẹ latari pe oun ni Alaṣẹ lori oriṣa gbogbo.
Oluwoo ni ko si iru ara toun ko le fi wọn da. Ọba Akanbi sọrọ yii niluu Isẹyin, nipinlẹ Ọyọ, nibi ayẹyẹ iranti gbajugbaja pidanpidan nni, Purofẹsọ Abiọla Peller, ẹni to doloogbe lọdun marundinlọgbọn sẹyin, eyi to waye niluu Isẹyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii. Ọba Akanbi to jẹ ọkan lara awọn ori-ade ti wọn fiwe pe sibi ayẹyẹ naa lakooko to n sọrọ lo koro oju sawọn ọba Yoruba pe awọn leku ẹda to n fa ọwọ idagbasoke ilẹ Yoruba sẹyin pẹlu oriṣa bibọ. O ni bi wọn ba ti yọwọ oun Oluwoo kuro, gbogbo iṣoro ati wahala ati ifasẹyin to n koju agbegbe naa ko sẹyin iwa ojukokoro owo, imọ-tara-ẹni-nikan paapaa nipa gbigbe aṣa ibọriṣa larugẹ lati jẹ atọna fun wọn lai naani ẹsin Islaamu ati ẹsin Kirisitẹni to n jẹ ki ọpọlọpọ ọba ṣina.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Oluwoo ilu Iwo lo kọkọ gba ẹsin Islaamu lọdun 1620 titi di oni, ẹsin naati tan kale kako, eyi to ti fopin si oriṣa bibọ.’ O waa gba awọn ọmọ orilẹ-ede yii, awọn ọmọlẹyin Kirisiti, awọn aafaa nla, lati gbohun adura soke, ati fawọn ọba wa gbogbo lati fopin si iwa ibọriṣa laarin wọn.
Ninu iwaasu gbajugbaja oniwaasi agbaye nni, Muhideen Ajani Bello, lo ti ṣapejuwe oloogbe Peller gẹgẹ bii ẹlẹyinju aanu ti ki i fẹ ki iya jẹ ọmọlakeji, to si tun di opo Isilaamu mu titi ti ọlọjọ fi de. O waa rọ awọn ọmọ, awọn alejo, mọlẹbi oloogbe lati wo awokọṣe rere oloogbe naa gẹgẹ bii apẹẹrẹ lati huwa rere. Ọkan lara ọmọ oloogbe naa to ba ALAROYE sọrọ nibi ayẹyẹ ikẹyin naa, Nikẹ Peller to jẹ gbajugbaja oṣere ori itage sọ pe baba oun kopa ribiribi lati le jẹ ki oun di ilu mọ-ọn-ka ninu iṣẹ toun yan laayo, oun ko si le gbagbe rẹ laelae. Aṣekagba idije ere bọọlu alafẹsẹgba laarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu nijọba ibilẹ mẹwẹẹwa ẹkun idibo Ariwa Ọyọ, eyi to ti bẹrẹ lati bii oṣu marun-un sẹyin ni wọn fi kadii ayẹyẹ naa. Ijoba ibilẹ Isẹyin lo ṣe ipo kin-in-ni ati ikeji ninu idije naa, ti ijọba ibilẹ Itẹsiwaju si ṣe ipo kẹta.