Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo wa ko le sun ka kọri sibi kan naa ni owe ti awọn Yoruba maa n pa. Bẹẹ ni wọn tun maa n sọ pe eyi wu mi ko wu ọ ni ko jẹ ka jọ pawo pọ fẹ obinrin.
Ṣugbọn awọn owe yii ko ṣiṣẹ lọdọ awọn oloṣelu ilẹ Naijiria, bi wọn ba ti n ṣatilẹyin fun oludijẹ kan, ohun ti wọn maa n fẹ ni ki gbogbo eeyan maa tẹle ẹni ti wọn n ṣatilẹyin fun yii.
Iru ẹ naa lo ṣẹlẹ lasiko idibo ọjọ Abamẹta Satide, ọjọ kejidinlogun yii ni Wọọdu kẹta, ni ibudo idibo kejidinlogun to wa ni Ọja Tuntun, niluu Ileefẹ, nipinlẹ Ọṣun, nibi tawọn tọọgi oloṣelu kan ti lọọ doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP. Wọn fiya nla jẹ wọn nitori wọn ko dibo fun alatilẹyin tiwọn.
Iya agbalagba kan fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa. Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, o sọ pe, ‘‘Mo debi laaarọ yii, wọn ni ẹni to ba ti mọ pe oun ko ni i dibo Ẹṣọ ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ APC nibi, ko ma duro. Mo kọkọ fẹẹ ṣọrọ, ṣugbọn gbogbo nnkan ija ni wọn ko dani. Mo ni ti mo ba sọrọ, wọn maa ni emi ni mo da ibi yii ru, mo si dibo mi, mo kuro.
‘‘Ko pẹ ti mo dibo ti mo de ṣọọbu mi ni wọn ba sare de, wọn ni wọn ti de, pe awọn kan ti waa fun wọn lọwọ pe ibo PDP la n di nibi, pe ki i ṣe ibo Ẹṣọ. Mo ba awọn eeyan to duro sọrọ pe ẹni to ba ti wu yin ni kẹ ẹ dibo fun, mo ni wọn ko le na yin, ẹ duro ki wọn tiẹ na yin wo. Lemi ba lọ si ṣọọbu mi.
‘‘Ni wọn ba pada de, ibọn, gbogbo nnkan ija oloro ni wọn ko wa. Wọn da ibo wa nu, wọn fọ apoti idibo, wọn bẹrẹ si i tẹ awọn iwe idibo wa mọlẹ, wọn si ko awọn kan lọ.’’
Bayii ni iya agbalagba yii ṣalaye, tawọn ọlọja ẹgbẹ rẹ si n kin in lẹyin pe awọn ọmọ ẹgbẹ APC lo waa da ibo awọn ru l’Ọṣun.