Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ni awọn ti pari eto lori atunṣe ọja to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta kan to wa lagbegbe ijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko, latari bijọba ipinlẹ naa ṣe fawọn ọlọja atawọn olokoowo to n ṣe kata-kara lọja ọhun ni gbedeke ọjọ mẹrinla pere, iyẹn ọsẹ meji, lati fi palẹ ẹru wọn mọ, ki wọn si wa ọja wọn sibomi-in, tori wọn lawọn maa wo ọja naa lulẹ patapata.
Kọmanda ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa Eko, iyẹn Rapid Response Squad, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, sọrọ lori idi tijọba ṣe fẹ ki katakata wọn lọọ pitu ọwọ ẹ lọja naa, ninu atẹjade kan, o ni:
“Ikọ awọn ọlọpaa meji ọtọọtọ, RRS ati tawọn igbimọ amuṣẹṣe to n ri sọrọ ayika, Lagos State Environmental and Special Offences Unit (Taskforce), eyi ti Ẹgbẹyẹmi dari, ni iroyin to n jade lati agbegbe Alaba Rago yii, paapaa latinu ọja naa, fihan pe awọn olubi ẹda kan ti sọ ọja Alaba Rago di ile ikẹrupamọsi fun nnkan ija oloro, o si ti di ibuba awọn ọdaran, ati pe ijọba fẹẹ tun ọja naa kọ si ti igbalode, ki wọn mu awọn horo si horo ati ibi kọlọfin ọja naa kuro, fun anfaani wọn araalu.
“Lọsẹ to kọja yii, ọpọ ibọn agbelẹrọ lawọn ọlọpaa, ẹka ti Ọjọ, hu jade nibi ti wọn tọju ẹ pamọ si lọja naa, bẹẹ lawọn olokoowo egboogi oloro tọwọ ba lọja ọhun jẹwọ pe ọja naa ti di ojuko ti wọn ti n fi awọn egboogi oloro ṣọwọ sawọn agbegbe mi-in lorileede yii, idi si niyi tijọba ko fi ni i jafara rara lati tu awọn olokoowo atapasofin yii ka lọja ọhun.
“Latari eyi, a ti ṣepade pẹlu gbogbo ọlọja tọrọ kan, a si ti fun gbogbo wọn ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati ko ọja wọn kuro patapata.”
Ẹgbẹyẹmi tun ṣalaye pe bijọba ṣe fẹẹ wo ọja yii tun maa dopin iwa ọbun ati ẹgbin ti wọn ti fi ba apa kan ọja naa jẹ, bakan naa lawọn ile onipako tawọn amugbo ati ọdaran mi-in maa n sapamọ si maa di afẹku.
O waa ṣekilọ pe kawọn araalu ma ṣe ronu pe ọrọ ẹsin tabi ẹya lo fa a o, ki i ṣe pe awọn gbe sẹyin ẹya kan tabi yan ekeji nipọsi, igbesẹ naa pọn dandan lati mu alaafia ati idẹrun ba araalu ni.