Ori aatan lawọn fijilante ti ri ọmọ tuntun kan he loru 

Monisọla Saka

Awọn ọdẹ agbegbe Díòbú, Port Harcourt, nipinlẹ Rivers, to n ṣọ adugbo, ti wọn n pe ni fijilante, ni Ọlọrun fi ṣe angẹli ọmọ tuntun jojolo kan ti wọn ri lori aatan ti wọn gbe e ju si laarin oru.

Awọn ni Ọlọrun lo lati doola ẹmi ọmọ tuntun naa ti wọn gbe ju sibi ti wọn n dalẹ si lagbegbe gareeji Mile 3.

Olori ikọ fijilante yii, Godstiem Ihunwo, to fọrọ naa lede latẹnu ajafẹtọọ ọmọniyan kan, Prince Wiro, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹta oru, lasiko tawọn n ṣe iwọde kiri, lawọn ri ọmọ to ti n ku lọ yii nibi ti wọn kẹ ẹ si lagbegbe Mile 3. Wọn ni ero ki i da rara ni adugbo tawọn ti ri ọmọ yii, wọn ni adugbo kan to maa n kun fun ero loju ọsan ni pẹlu.

O tẹsiwaju pe ẹkun ọmọ ti ko ti i le ju bii wakati mẹfa to dele aye lọ tawọn n gbọ lọhun-un lọhun-un, lo mu kawọn ọdẹ ti wọn n yi adugbo kiri wo apa ibẹ, ohun ẹkun rẹ yii lo si ṣatọna bawọn ṣe mọ ọgangan ibi tọmọ naa wa gan-an. Nibẹ lo ni wọn ti ri ọmọ tuntun ọhun pẹlu ibi to gbe waye ti wọn ko ti i ge e kuro lara rẹ, ti wọn fi aṣọ kan we lara.

Ninu ọrọ tiẹ, Prince Wiro, rọ ijọba ipinlẹ Rivers, lati paṣẹ fawọn agbaṣẹṣe ti ina ojupopo agbegbe Ikwerre Street, wa ni ikawọ wọn lati ri i pe wọn n tanna ọhun lalaalẹ. O loun ti ṣakiyesi pe awọn ina ọhun ki i si ni titan ni gbogbo alẹ.

O waa gba awọn ọdọbinrin ti wọn n gboyun airotẹlẹ nimọran lati dawọ awọn iwa ọdaju ti wọn n hu yii duro, o ni ki wọn wa iranlọwọ lọ sọdọ awọn ileeṣẹ ijọba, tabi ti aladaani, o ni eleyii  san ju ki wọn maa sọ ọmọ to n bọ wa saye tiẹ, ti ko mọ nnkan kan nu lọ.

 

Leave a Reply