Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ori lo ko eeyan mejidinlogun yọ lọwọ iku ojiji lopopona Ajaṣẹ-Ipo, nipinlẹ Kwara, lowurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, nigba ti ọkọ bọọsi akero to ko wọn gbina.
ALAROYE gbọ pe bọọsi elero mejidinlogun kan to ko ero bamu lo gbera niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lowurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, to si n ko wọn lọ si ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun. Ṣugbọn lakooko ti ọkọ ero ọhun de abule kan ti wọn n pe ni Ọkọ, lopopona Ajaṣẹ-Ipo, ni ọkọ naa deede gbina. Ori lo si ko gbogbo awọn ero inu ọkọ naa yọ, ko si ẹni to ku, ṣugbọn gbogbo ẹru wọn lo jona raurau.