Ori ko Sẹnetọ Ọṣun yọ lọwọ awọn agbebọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ori lo ko aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Ila-Oorun Ọṣun, Sẹnetọ Adelere Oriolowo, yọ lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti awọn agbebọn ya bo ibi to ti n ṣepade pẹlu awọn eeyan agbegbe rẹ.

ALAROYE gbọ pe ilu Ikire, nijọba ibilẹ Irewọle, ni Oriolowo lọ lati ba awọn eeyan rẹ ṣepade papọ lati le sọ awọn nnkan to ni lọkan fun wọn fun ọdun tuntun yii, ṣugbọn lojiji lawọn ẹruuku ọhun ya de.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ Oriolowo, Adams Adedimeji ṣalaye pe bi awọn eeyan naa ṣe de ni ibọn n ro lakọlakọ, ti wọn si doju kọ ọgangan ibi ti aṣofin agba naa duro si.

Kia la gbọ pe wọn fẹyin pọn oloṣelu yii kuro nibẹ, sibẹ, ṣe lawọn agbebọn ọhun doju ibọn kọ mọto rẹ, ti gbogbo gilaasi mọto naa si fọ silẹ.

Ilu Oṣogbo la gbọ pe wọn gbe Oriolowo wa lẹyin iṣẹlẹ naa, ti awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii lori ẹ.

Leave a Reply