Faith Adebọla
Aarẹ orileede Naijiira, Mohammadu Buhari, ti gbe aba eto iṣuna owo tijọba apapọ yoo na lọdun 2022 kalẹ siwaju ileegbimọ aṣofin ilẹ wa, tiriliọn mẹrindinlogun naira (N16.39 trillion) lo lawọn maa na.
Owurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni Aarẹ Buhari ka aropọ aba iṣuna naa setiigbọ awọn aṣofin ọhun, ninu ipade akanṣe ti awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin ati awọn sẹnetọ ṣe papọ, gbọngan ipade awọn aṣofin agba (sẹnetọ) nipade naa ti waye, ile naa si kun fọfọ.
Ṣaaju ni olori awọn aṣofin ati alaga ipade ọhun, Sẹnetọ Ahmed Lawan, ti kede pe Aarẹ, Igbakeji Aarẹ ati awọn ọmọ igbimọ iṣakoso rẹ wa nitosi lati ka aba eto iṣuna ọdun to n bọ fawọn aṣofin gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.
Ninu alaye rẹ, Buhari ni iṣiro naira mẹwaalenirinwo aabọ si dọla kan lawọn fi ṣe odiwọn paṣipaarọ naira ninu aba eto iṣuna naa, o ni iṣiro dọla mẹtadinlọgọta ti wọn ta barẹẹli epo rọbi lọja agbaye lawọn fi ṣeto bọjẹẹti ọhun.
“Ọrọ aabo ati ẹṣọ ologun ilẹ wa lo ṣi n gbawaju ninu afojusun wa, tori gbọin-gbọin la ṣi rọ mọ ojuṣe ijọba lati pese aabo fun ẹmi, dukia ati awọn okoowo jake-jado orileede yii. A gbọdọ ri i daju pe awọn ọmoogun wa lọkunrin ati lobinrin nileeṣẹ ologun, ti ọlọpaa ati awọn ẹṣọ alaabo mi-in ni awọn nnkan eelo ati irinṣẹ ti wọn nilo, ki wọn ri owo-oṣu gba deedee, ka si ṣe koriya fun wọn.”
Buhari bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe yẹ ko lọ, owo tijọba lagbara ati ẹtọ lati pa wọle labẹnu ati lẹyin odi jẹ tiriliọnu mẹtadinlogun aabọ naira (N17.7 trillion), ṣugbọn tiriliọnu mejila aabọ pere lo ṣe e gba to si ṣe e pin lara owo yii.
Lẹyin eyi ni aarẹ sọ pe ifọsiwẹwẹ bijọba yoo ṣe pawo wọle ati bi wọn yoo ṣe nawo ti wa ninu adipọ iwe toun ko kalẹ siwaju awọn aṣofin naa, isọri-isọri ati lẹka-jẹka, ni wọn ṣe akọsilẹ awọn aba naa.
O lo anfaani naa lati gboṣuba fawọn aṣofin apapọ naa fun bi wọn ṣe duro gbaagbaagbaa lẹyin iṣakoso ohun, o lẹni to ṣee fọkan tẹ ni wọn, o si ṣeleri pe bi eto iṣuna naa ba tete di ofin, ireti wa pe awọn ọmọ Naijiria maa too fẹyinti lati jadun ijọba awa-ara-wa to wa lode yii.