Awọn ẹbi oloogbe, Yinka Odumakin, ti ya ọjọ mẹta, iyẹn ọjọ kejilelogun, kẹtalelogun ati ikẹrinlelogun, oṣu kẹrin yii, sọtọ fun ayẹyẹ isinku ajijagbara naa.
Gẹgẹ bi atẹjade kan lati ọdọ iyawo oloogbe naa, Dokita Joe Odumakin, to tẹ ALAROYE lọwọ, eyi to pe ni ‘Eto isinku Yinka Odumakin’ lo ti sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin yii, ni wọn yoo ṣe isin bibu ọla fun un ati isin alẹ Onigbagbọ, nibi ti wọn yoo ti tẹ oku rẹ nitẹ ẹyẹ, eyi ti yoo waye ni Police College to wa ni Ikẹja, niluu Eko, laago mọkanla si aago mẹrin irọlẹ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn yoo gbe oku akọni ajijagbara naa lati ilu Eko lọ si ilu abinibi rẹ ni Moro, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun. Aisun Onigbagbọ yoo waye nibẹ fun oloogbe yii naa ni ileewe girama Origbo Anglican Grammar School, niluu Moro. Bẹẹ ni isin ẹyẹ titan abẹla fun un yoo waye lọjọ yii kan naa.
Ni deede aago mẹjọ aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin yii, ni wọn yoo tẹ oku rẹ ni itẹ ẹyẹ si Origbo Anglican Grammar School yii kan naa.
Aago mẹwaa aarọ ni isin idagbere yoo si waye fun un, lẹyin eyi ni wọn yoo gbe e wọ kaa ilẹ lọ nibi eto ti yoo jẹ ti awọn mọlẹbi nikan.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu kẹrin ọdun yii ni ajijagbara naa pa oju de si ọsibitu ijọba to wa niluu Eko, nibi to ti n gba itọju arun Korona to mu un. Ni nnkan bii aago mọkanla ku ogun iṣẹju lọjọ naa ni Yinka Odumakin mi ini ikẹyin nileewosan naa.
Ọmọ bibi ilu Moro, nipinlẹ Ọṣun, ni, o fi iyawo atọmọ, awọn obi pẹlu awọn ẹgbọn meji saye lọ.