Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina Adegboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe bi oun ko ṣe ja awọn araalu kulẹ ninu gbogbo ileri ti oun ṣe fun wọn lọdun mẹta ataabọ sẹyin pẹlu owo perete to n wọle sipinlẹ Ọṣun ni yoo jẹ ọpakutẹlẹ ijawe olubori oun ninu idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.
Nibi eto kan ti ibudo to n ri si ibaṣepọ awọn araalu, State’s Civic Engagement Center, ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn oniburẹẹdi, ẹka tipinlẹ Ọṣun, ni gomina ti sọ pe ẹri-maa-jẹ-mi-nso ni oniruuru aṣeyọri tiṣejọba oun ṣe kaakiri.
Oyetọla, ẹni ti Oludamọran pataki rẹ ni ẹka naa, Ọlatunbọsun Oyintiloye, ṣoju fun ṣalaye pe ẹru ko ba oun rara nitori ọwọ Ọlọrun ati awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni atunyansipo gomina oun wa.
O ni lai fi ti owo perete to n wọle si asunwọn ijọba lọwọlọwọ bayii ṣe, oun ko ni i dawọ duro lori oniruuru ọna ti eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun yoo fi gbẹnu soke si i.
Oyetọla, ẹni to ṣapejuwe awọn araalu gẹgẹ bii opo kan ṣoṣo tiṣejọba oun duro le lori latigba to ti de ori aleefa, fi da awọn araalu loju pe gbogbo nnkan to ba maa gba loun yoo fun un lati le mu ki aye rọrun fun gbogbo eeyan.
O sọ pẹlu idaniloju pe ko si oludije kankan latinu ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun to ku, to le koju oun loṣu Keje, nitori awọn araalu ko fẹ ijọba ti yoo tun fa wọn sẹyin.
O ni oun ko ni i sinmi rara ni kete ti oun ba ti pada wọle gẹgẹ bii gomina, gbogbo awọn iṣẹ rere ti oun ti n ṣe loun yoo tẹsiwaju ninu wọn, bẹẹ ni alaafia pupọ yoo tubọ wa fun imugbooro awọn oniṣẹ ọwọ.
Ninu ọrọ rẹ, Alaga ẹgbẹ naa, Bakare Ganiyu, gboriyin fun gomina lori oniruuru awọn iṣẹ idagbasoke to n ṣe. O fi da a loju pe gbagbaagba lawọn ọmọ ẹgbẹ naa yoo duro ti i lasiko idibo to n bọ yii.