Osun 2022: Ọmọọṣẹ Arẹgbẹṣọla fẹgbẹ APC silẹ, o darapọ mọ PDP

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọṣun laye iṣẹjọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, Barisita Kọlapọ Alimi, ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC bayii, o si ti darapọ mọ ẹgbẹ PDP.
Ọkan lara awọn abẹnugan igun ẹgbẹ oṣẹlu APC l’Ọṣun ti wọn n pe ara wọn ni The Osun Progressives (TOP) ni Alimi tẹlẹ, o si ti kọkọ figba kan sọ pe oun ko le kuro ninu ẹgbẹ naa laelae ko too waa di pe o bọ sabẹ Ọnburẹla lọjọ Wẹsidee ọsẹ yii.
Nigba to n sọrọ nibi eto naa, eleyii to waye ni sẹkiteriati ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Oṣogbo, Alimi sọ pe alabosi ti inu rẹ ki i fi igba kankan dun ni Gomina Oyetọla. O ni pẹlu bo ṣe jẹ pe ki i ṣe oloṣelu rara, sibẹ, Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla fi i ṣe olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina fun odidi ọdun mẹjọ, ṣugbọn ibi lo fi san an fun un.
Alimi sọ siwaju pe gbogbo ẹni ti Oyetọla ba ti ri i pe o sun mọ Arẹgbẹṣọla ni yoo mu ni ọta kiakia, to si ti gbagbe gbogbo laalaa ti awọn ṣe fun un ko too fi gomina ipinlẹ Ọṣun.
O sọ siwaju pe ohun ko ti i ri ẹni to ni ahun to Gomina Oyetọla, o ni o fi iyawo rẹ ṣe dẹligeeti fun idibo abẹle nipinlẹ, o si tun fi ọmọ rẹ ṣe dẹligeeti ninu idibo gbogboogbo ẹgbẹ APC.

Barisita Alimi waa fi da Sẹnetọ Ademọla Adeleke to jẹ oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP loju pe fọọfọ ni apoti ibo rẹ yoo kun kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
O ni oun ati awọn ololufẹ oun ti awọn le ni ẹgbẹrun meji aabọ lati ijọba ibilẹ mọkandinlogun nipinlẹ Ọṣun yoo ṣiṣẹ takuntakun fun ijawe olubori Adeleke, o si daju pe iyatọ ti yoo wa laarin ibo oun ati Oyetọla lasiko yii yoo le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un.
Ninu ọrọ tirẹ, Ademọla Adeleke fi idunnu rẹ han si bi Alimi ṣe gba lati ṣiṣẹ papọ pẹlu rẹ, o ni ojoojumọ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu loriṣiiriṣii n wọ wọnu ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun nitori ẹgbẹ oṣelu PDP nikan lo le fun wọn ni erejẹ ijọba tiwa-n-tiwa to poju owo.

Leave a Reply