Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje ni wọn ti wa nikaawọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, lẹyin ti wọn fipa ba ọmọbinrin kan lo pọ, ti wọn si tun digun ja a lole niluu Igbọkọda, n’ijọba ibilẹ Ilajẹ.
Ninu alaye ti Alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ṣe fawọn oniroyin lasiko to n ṣe afihan awọn afuarsi naa ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, o ni ṣe lawọn tọwọ tẹ ọhun tun de awọn ẹsọ Amọtẹkun mọlẹ, ti wọn si tun ṣe wọn leṣe nibi ti wọn ti fẹẹ fi pampẹ ofin gbe wọn ni Igbọkọda.
Adelẹyẹ ni lọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni awọn janduku ọhun da ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan lọna lasiko to n lọ silẹ, ti wọn si fi tipatipa ba a laṣepọ, bẹẹ ni wọn tun gba awọn nnkan ini rẹ lọ.
O ni loju-ẹsẹ l’ọmọbinrin ta a n sọrọ rẹ yii ti mori le ọfiisi ẹṣọ Amọtẹkun to wa niluu Igbọkọda, lati fẹjọ awọn ọdaran naa sun, to si sọ fun wọn pe oun mọ ọkan ninu wọn bii ẹni m’owo.
Eyi lo mu ki awọn Amọtẹkun sare lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn gbogbo wọn ti sa lọ ki wọn too debẹ.
Adelẹyẹ ni latigba naa lawọn ti n dọdẹ wọn titi ti obinrin ti awọn forukọ bo laṣiiri ọhun fi pada wa lopin ọsẹ to kọja yii pe oun ti kofiri awọn ti wọn ṣe ikọlu s’oun nibi kan.
Bi awọn Amọtẹkun ṣe n de ibuba awọn afurasi ọdaran naa lo ni wọn doju ija nla kọ wọn, ti wọn si de mẹrin ninu wọn mọlẹ pẹlu okun, wọn ṣa wọn ladaa yannayanna, ti wọn si tun fi ọpọ iya ti ko ṣee fẹnu sọ jẹ wọn.
Wọn ri meji mu ninu awọn janduku ọhun mu lẹyin-o-rẹyin, awọn ti wọn ri mu lọjọ naa ni wọn ṣe atọna bi ọwọ tun ṣe tẹ awọn meje mi-in.
Adelẹyẹ ni ile ọga awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ti wọn porukọ rẹ ni Moshood Kazeem, lawọn ti pada ri foonu ti wọn gba lọwọ ọmọbinrin ti wọn fipa ba sun naa pada.
O ni Kazeem jẹwọ fawọn pe awọn ti pin owo ti awọn gba lọwọ ọmọbinrin yii laarin ara awọn, ti olukuluku si ti na tirẹ.
O ni nibi ti awọn ti n yẹ ile Kazeem wo lọwọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan tun ti doju ija kọ awọn Amọtẹkun, ti wọn si n yinbọn kikankikan, ṣugbọn ti awọn pada kapa wọn.
Awọn nnkan ija bii ibọn agbelẹrọ to ni ọta ninu, ada, oogun loriṣiiriṣii lo ni awọn ko jade nile Kazeem to jẹ olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa.
Ọga ẹsọ Amọtẹkun ọhun ni ko si ootọ ninu iroyin kan to kọkọ jade pe awọn lọọ ṣe akọlu si awọn ọdọ kan nibi ti wọn ti n ṣe iṣọmọlorukọ, o ni ajọṣepọ to dara wa laarin Amọtẹkun atawọn eeyan ilu Igbọkọda.
Nigba to n ṣalaye ohun to foju wina lọwọ awọn janduku ọhun, ọmọbinrin ta a n sọrọ rẹ yii ni ayẹyẹ oku kan loun waa ṣe nipinlẹ Ondo, lẹyin ti ayẹyẹ naa pari lo ni oun pinnu ati ya ki iya oun to n gbe niluu Ayetoro, nijọba ibilẹ Ilajẹ, ki oun too pada síbi ti oun ti wa.
O ni b’oun ṣe n sọkalẹ ninu ọkọ loun ri awọn janduku kan ti wọn yọ ibọn si oun, wọn wọ oun lọ sinu ile akọku kan, nibi ti ọkan ninu wọn ti fipa ba oun sun, lẹyin ti wọn ti kọkọ gba foonu ati gbogbo owo to wa lọwọ oun.
Kazeem ninu alaye tirẹ ni loootọ lawọn da obinrin naa lọna, tawọn si gba foonu ati owo to wa lọwọ rẹ, o ni oun gan-an loun fipa ba a sun lẹyin ti awọn gba awọn nnkan ini rẹ tan.
Adelẹyẹ ni gbogbo awọn afuarsi ọhun lawọn maa foju wọn b’ale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.