Wọn fẹsun ayederu iwe-ẹri kan Ọmọọba Adebomi to fẹẹ dupo ọba Ararọmi Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa lati ẹkun kẹtadinlogun (Zone 17), Akurẹ, ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ ọmọọba kan, Ọgbẹni Babalọla Adebomi, pẹlu ẹsun pe lo ayederu iwe-ẹri lati gba’ṣẹ lọdọ ìjọba ipinlẹ Ekiti.

Ọmọọba Adebomi, ẹni to wa lara awọn to n dije lati jẹ oba ilu Ararọmi-Ekiti, nijọba ibilẹ Ijero,  ni awọn ọlọpaa ṣalaye pe ọwọ awọn tẹ ni Ado-Ekiti, lẹyin iwadii ẹsun kan ti wọn fi kan an pe o ṣe agbelẹrọ iwe-ẹri Yunifasiti Ibadan.

Alukoro ọlọpaa ni ẹkun kẹtadinlogun, Ọgbẹni Adeoye Hakeem, sọ pe Ọmọọba Adebomi, ni awọn ọmọ bibi ilu rẹ ti kọkọ kọwe ẹsun kan mọ pe iwe-ẹri to fi gba’ṣẹ lọdọ ijọba ipinlẹ Ekiti jẹ ayederu, wọn ni ọkunrin naa ko lọ si Fasiti Ibadan to n gbe iwe rẹ kiri.

O fi kun un pe Adebomi, to jẹ ọkan lara awọn ọga agba nileewosan  ẹkọṣẹ ipinlẹ Ekiti, ti wa lahaamọ niluu Akurẹ, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọo tin koju iwadi lọwọlọwọ.

Tẹ o ba gbagbe, awọn ọmọ ilu Ararọmi-Ekiti ni wọn ti kọkọ gun le iwọde kan lọ si ileegbimọ aṣofin ati ileeṣẹ to n mojuto ọrọ oye nipinlẹ Ekiti, pe kijọba dawọ duro lati fi Ọmọọba Adebomi jọba ilu naa pẹlu alaye peayederu ni  iwe-ẹri to wa lọwọ rẹ.

ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ si i fọrọ wa a lẹnu wo lori ẹsun naa, pẹlu ileri pe wọn yoo gbe e lọ si kootu to ba jẹbi ẹsun ọhun.

Leave a Reply