Ṣẹyin naa ti gbọ ohun ti ọba ilu Fiditi ti wọn rọ loye ṣe?

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti wọn ti rọ Onifiditi tilu Fiditi loye, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ lori ọrọ oba ilu naa gan-an ni bayii pẹlu bi ori ade ọhun, Ọba Oyelẹyẹ Sakirudeen, ṣe faake kọri, o ni lèmọ̀ọ́mù  kan ko le le oun kuro lori itẹ awọn baba nla oun.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun (24), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ, to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, fi idajọ wọn le ori ade naa kuro nipo ọba.
Mẹsan-an ninu awọn alẹ́nulọ́rọ̀ lori ọrọ oye ọba Fiditi, Ọgbẹni Samuel Ogunkunle pẹlu Bayọ Oyewale, atawọn meje mi-in, ni wọn pẹjọ ta ko ijọba Ọba Sakirudeen, wọn loun kọ nipo naa tọ si.
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo gbe ọpa aṣẹ le olujẹjọ naa lọwọ gẹgẹ bii Onifiditi tilu Fiditi lọjọ kejidinlogun (18), oṣu Kẹwaa, ọdun 2021.
Latigba naa lawọn alatako ọba naa si ti dènà de e ni kootu, wọn ni ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ko fipo naa silẹ nitori ọna to gba gori itẹ lodi patapata si ilana ti wọn fi n yan ọba ilu naa.
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ati meji ninu awọn kọmiṣanna rẹ, kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ pẹlu kọmiṣanna fọrọ ofin ati eto idajọ naa wa lara awọn ti wọn gbe lọ si kootu lati jẹjọ ọhun, nigba ti awọn mẹta yooku, Ademọla Akande, Depo Oguntoyin, ati Kunle Oniyitan, jẹ ara awọn afọbajẹ ilu naa.
Ohun ti awọn olupẹjọ fẹ naa nile-ẹjọ pada ṣe pẹlu bi Onidaajọ K.B. Ọlawọyin ti i ṣe adajọ kootu naa ṣe paṣẹ pe ki Ọba Sakirudeen fipo silẹ kiakia.
Ṣugbọn lọjọ Wẹsidee ọhun kan naa, lọba naa ti sọ pe ọrọ ko ti i pari sibẹ, nitori ni toun, oun ko ni í fi ipo silẹ, n lo ba gba ile-ẹjọ kotẹmilọrun lọ, o ni ki ile-ẹjọ nla naa fi agbara rẹ pa idajọ ti wọn fi rọ oun loye rẹ, ki oun le tẹsiwaju lori itẹ ọba titi oun yoo fi darapọ mọ awọn baba nla oun.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ yii, Amofin
Fẹmi Alamu, ti i ṣe agbẹjọro ọba naa, fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn ti pẹjọ kotẹmikọrun lori ọrọ naa, nitori iyansipo Ọba Sakirudeen gẹgẹ bii Onifiditi wa ni ibamu pẹlu ofin ati ilana ifọbajẹ ilu naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Wọn ti gbagbe pe gomina lo sọ ipo Onifiditi di ipo ọba lati ipo baalẹ to wa tẹlẹ, inu awọn araalu si dun si i gidigidi, nitori ohun to ti n kọ wọn lominu lati ọdun pipẹ lọrọ baalẹ ti wọn n pe olori ilu Fiditi tẹlẹ. gomina naa lo si fọwọ si bi Ọba Sakirudeen ṣe gori itẹ”.
Ni bayii ti ọba ti ile-ẹjọ rọ loye yii paapaa ti gbe awọn alatako rẹ lọ sile-ẹjọ to tun ga ju eyi to da a lẹbi lọ, gbogbo bi igbẹjọ tuntun naa ba ṣe n lọ si pata l’ALAROYE yoo maa fi to yin leti.

Leave a Reply