Ẹfun abeedi, ọmọ Naijiria yii luyawo ẹ pa niluu oyinbo, eyi lohun to lo ṣe

Monisọla Saka

Ibinu odi ti mu ki ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Naijiria toun pẹlu awọn ẹbi ẹ ṣẹṣẹ ko lọ si ilẹ UK, Olubunmi Abọdunde, fi pako iṣere ọmọ wọn lu iyawo ẹ, Oloogbe Taiwo Abọdunde pa, nile wọn to wa lagbegbe Suffolk, orilẹ-ede United Kingdom.

Lọdun 2022, ni tọkọ-taya ọhun pẹlu awọn ọmọ wọn mẹta de siluu oyinbo, amọ to jẹ ọrọ nipa bukata gbigbọ ninu ile ati ẹsun pe iyawo n fọbẹ ẹyin jẹ ẹ niṣu lo saaba maa n dija silẹ laarin wọn.

Ija to waye laarin ọkọ atiyawo yii ṣaaju ọjọ tiṣẹlẹ naa waye ti mu kawọn ọlọpaa kilọ pe ki ọkunrin naa yago fun iyawo ẹ ati ile wọn, amọ to jẹ ọjọ keji to yọju sile naa lo binu lu ọmọbinrin naa pa.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ gbe afurasi naa lo sile-ẹjọ. Agbefọba, Simon Spence KC, si sọ fun adajọ pe awọn ọlọpaa to n ṣọ Ọgbẹni Abọdunde lẹyin ti wọn ni ko yago funyawo ẹ gbọ gbaa gbaa gbaa ninu ile naa, ṣugbọn ki wọn too ribi wọle, nnkan ti yiwọ, o ti fibinu lu obinrin naa pa.

Nirọlẹ mọ alẹ ọjọ naa ni wọn gba beeli ọkunrin yii, ti wọn si tu u silẹ pẹlu ikilọ pe ko yẹra kuro nile wọn na, ki o ma si ṣe de sakaani iyawo rẹ. Ṣugbọn lẹyin ti ọkunrin yii pari iṣẹ alẹ to n ṣe lọwọ ni Tesco, lai fi ti ikilọ awọn ọlọpaa ṣe, ile ti wọn ni ko yẹra fun yii lo mori le, pẹlu awijare pe oun fẹẹ lọọ mu foonu oun nibẹ.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju laaarọ ọjọ naa ni awọn ọlọpaa meji de sile wọn lati gba akọsilẹ nnkan to ṣokunfa ija to waye laarin wọn lalẹ mọju ọjọ naa, amọ to jẹ pe gbaa gbaa gbaa ni ariwo to gba inu ile wọn kan, tawọn yẹn n gbọ lati ita ti wọn wa.

Iṣẹju marundinlogoji lẹyin rẹ, iyẹn ni aago mẹwaa aarọ ku iṣẹju marun-un, ni awọn ọlọpaa mejeeji too ribi jalẹkun wọle, lẹyin ti wọn gba aṣẹ lọwọ ọga wọn, nibẹ ni wọn ti ba oku obinrin ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) yii nilẹẹlẹ, lẹgbẹẹ ẹnu ọna ati-wọle wọn to ti ṣe e ṣakaṣaka.

Ayẹwo iku to pa oloogbe fi han pe niṣe lọkunrin naa ti kọkọ fun un lọrun titi to fi ṣubu lulẹ. Lẹyin naa lo bẹrẹ si i gun un mọlẹ, pako iṣere tawọn eeyan maa n gbẹsẹ le lati fi rin kaakiri (Skateboard), to jẹ tawọn ọmọ ẹ lo kuku waa fi lu u pa. O fi ibinu fọ pako yii mọ iyawo ẹ debii pe pako iṣere ọhun fọ bajẹ ni.

Gẹgẹ bi alaye tawọn agbofinro agbegbe Suffolk ṣe, owu jijẹ ati fifi ẹsun kan iyawo ẹ pe o n yan ale ti wa lara ọkunrin naa tipẹ. Lọpọ igba ni wọn ni awọn ọlọpaa ti da si ọrọ aarin wọn, ti wọn si ti n wadii nipa ilukulu ati ija gbogbo igba to maa n waye laarin oun atiyawo ẹ, ko too pada wa lu u pa.

Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, lawọn ọlọpaa fi panpẹ ofin gbe e, lasiko ti wọn ba iyawo ẹ ti ete rẹ bẹ latara lilu bii aṣọ ofi nile wọn to wa ni Newmarket, Suffolk, lorilẹ-ede UK.

Ileeṣẹ ti wọn ti n ṣetọju awọn arugbo atawọn to nilo itọju pataki lagbegbe Cambridge, ni oloogbe ti n ṣiṣẹ latigba ti wọn ti de lati Naijiria, amọ ti ọkọ to jẹ onimọ ẹrọ ko ri iṣẹ ẹnjinnia to mọ yii, to si tibẹ n ṣiṣẹ ọlọdẹ ni Tesco ati Wickes.

Ileewosan ni wọn kọkọ mu afurasi lọ lẹyin ti wọn fofin gbe e fẹsun apaniyan lati le ṣayẹwo ọpọlọ fun un.

Adajọ Martyn Levett, ti paṣẹ pe ki wọn fi ọkunrin yii satimọle, ki idajọ too waye lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an lọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ti oloogbe ti n ṣiṣẹ ṣapejuwe rẹ bii ẹni ti gbogbo wọn fẹran. Wọn gba a laduura pe Ọlọrun yoo duro ti awọn ọmọ ati ẹbi to fi silẹ.

 

Leave a Reply