Ebi buruku lọkọ mi fi n pa emi atawọn ọmọ, mi o fẹ ẹ mọ-Raheemat

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe owe Yoruba kan lo sọ pe ebi ki i wọnu kọrọ mi-in wọ ọ, o jọ pe eyi ni iyaale ile kan, Rọheemat Tijani, ro papọ to fi ni oun ko fẹ ọkọ oun, Teslim, mọ. O ni ebi buruku ni ọkunrin naa fi n pa oun ati ọmọ oun, ko si si ifẹ mọ. Lo ba rawọ ẹbẹ si adajọ pe ki wọn jọwọ jare, tu igbeyawo naa ka, ki onikaluku maa lọ lọtọọtọ.

Kootu kọkọ-kọkọ kan to fikalẹ sagbegbe Akérébíata, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lobinrin yii gbe ọkọ rẹ lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin yii.

Olupẹjọ naa, Rọheemat, sọ niwaju adajọ kootu ọhun pe lati bii ọjọ pipẹ sẹyin lọkọ oun ko ti fowo ounjẹ silẹ, bẹẹ ni ko si ra ounjẹ silẹ toun ati ọmọ le jẹ.

Nigba to n wi awijare tirẹ, ọkọ Rọheemat to jẹ olujẹjọ sọ fun ile-ẹjọ pe oun ko ṣetan lati kọ iyawo oun, ati pe irọ ni iyaale ile naa n pa.

O ni, “Oluwa mi, ibi iṣẹ oojọ mi ni mo lọ ti mi o ba a nile mọ, nigba ti mo pe baba rẹ pe mi o ba iyawo mi nile mọ, o ti ko jade, ki lo n ṣẹlẹ, baba rẹ ni iyawo mi wa nile awọn, ati pe o sọ fawọn mọlẹbi pe ọkọ lo le oun jade. Gbogbo ẹru rẹ lo ti ko jade bayii.

“Nigba to ya awọn mọlẹbi ni awọn ko mọ ibi to wa, a fi bi mo ṣe ri iwe kootu pe iyawo mi fẹẹ kọ mi silẹ ki n wa sile-ẹjọ, titi ti di bi mo ṣe n ṣọrọ yii, mi o mọ ẹṣẹ ti mo ṣẹ iyawo mi to fi ko jade nile’’.

Onidaajọ Yunusa Abdullahi beere lọwọ ọkọ pe, ” ṣe iwọ ṣi nifẹẹ iyawo rẹ, to o si n fẹ atunṣe.” Ọkọ dahun pe bẹẹ ni.

Ni adajọ ba sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Leave a Reply