Ọwọ ba Fulani mẹta nibi ti wọn ti n da awọn eeyan lọna niluu Tede

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Ọwọ awọn ẹṣọ fijilante ti ba awọn afurasi ọdaran Fulani mẹta kan, Yakubu Mohammed, ẹni ogun ọdun, Saleh Magu, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati Ibrahim Legi, ẹni ọdun mẹtalelogun. Ọna to lọ lati ilu Tede si Ọjẹ-Owode, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn ti mu wọn.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni niṣe lawọn afurasi mẹtẹẹta yii n fibọn ati ada halẹ mọ awọn arinrin-ajo atawọn agbẹ to n gba ọna naa kọja lọ soko wọn, wọn si n ja wọn lole dukia wọn.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, tọwọ palaba wọn segi, itosi abule Ayefẹlẹ ni wọn lawọn janduku naa duro si, ti wọn si n ba iṣẹ laabi wọn lọ.

Ọgbẹni Ademọla Ọlaworẹ, to jẹ ọga agba awọn fijilante agbegbe naa ṣalaye fakọroyin wa pe o ti to ọsẹ mẹta sẹyin tawọn ti gbọ oriṣiiriṣii iroyin buruku nipa iwa ọdaran tawọn amookunṣika ẹda naa n hu lagbegbe ọhun, ṣugbọn bawọn ṣe n dọdẹ wọn ni wọn sa kiri lati ibikan si omi-in.

Ọlawọọre ni oju ọna kan to lọ si adugbo Ayefẹlẹ lawọn Fulani ọdaran yii fẹẹ fi ṣe ibuba wọn, wọn ti n mura lati kọ Gaa kan sibẹ kọwọ too tẹ wọn.

O ni igba kẹta ree tawọn n gba adugbo naa kọja, tawọn n wa wọn kiri, laimọ pe ori igi ni wọn sa pamọ si.

Lọjọ ti wọn mu wọn yii, Ọlawọọre ni awọn ko gba ọna ti gbogbo eeyan maa n gba, ki wọn ma baa fura, lojiji si lawọn yọ si wọn, bi wọn ṣe ri awọn ni wọn bẹrẹ si i yinbọn, bo tilẹ jẹ pe ibọn naa ko le jiṣẹ ti wọn ran an.

Ẹyin naa ni wọn gba awọn ohun ija oloro ti wọn gbe dani, lara rẹ ni ibọn, ida oloju meji, ada, ati ọpọ oogun abẹnugọngọ. Wọn lawọn Fulani yii jẹwọ pe ipinlẹ Katsina lawọn ti wa, ati pe loootọ lawọn n da awọn eeyan lọna lagbegbe naa.

Ọlawọre ni gbara tawọn ba ti pari iwadii lawọn yoo fa wọn le awọn ọlọpaa teṣan Tede lọwọ, awọn si nigbagbọ p’awọn ọlọpaa yoo fẹsẹ ofin to ọrọ naa bo ṣe yẹ.

Ọlawọọre waa gba awọn araalu nimọran lati yẹra fun irin alẹ ati aajin lasiko yii, nitori awọn apamọlẹkun-jaye wọnyi.

Leave a Reply