Ẹ sọ fun ijọba Buhari ko bọwọ f’ofin o, ko lẹtọọ lati ni ki wọn fi tipatipa gbe Sunday Igboho wa si Naijiria-Lọọya Igboho

Jọkẹ Amọri

Bi ki i baa ṣe yiyọ Ọlọrun, ati gbogbo ipa ti awọn majẹ-o-bajẹ ṣa, ijọba Naijiria iba ji ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho, gbe de Naijiria ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe fi to yin leti ninu iroyin ta a gbe jade pe ijọba Buhari n wa gbogbo ọna lati gbe Sunday Igboho pada si Naijiria, boya ọna naa tọ tabi ko tọ. Ootọ yii tubọ fara han ninu iṣẹlẹ to waye ni orileede Olominira Benin. Ọkan ninu awọn agbẹjọro Oloye Igboho to fi ilẹ France ṣe ibugbe, ṣugbọn to wa si Naijiria nitori ẹjọ naa, Dokita Oluṣẹgun Malik Falọla ṣalaye f’ALAROYE lori foonu lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nipa ohun to n ṣẹlẹ gan-an.

Agba agbẹjọro naa ni, ‘‘Mo fi Alukuraani bura, mo fẹrẹ le daku nigba ti mo gbọ pe ijọba Naijiria fẹẹ ji Sunday Igboho gbe pada si ilẹ Naijiria. Oju-ẹsẹ ni mo ti gbe mọto ti mo lọọ ba awọn ti wọn gbe e pamọ, mo si kilọ fun wọn pe ọrun ijọba Benin ni Sunday wa, bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si i, wahala to maa da silẹ ko ni i tan nilẹ.

Nigba ti Akoroyin wa beere boya o ṣee ṣe loootọ lati fipa ji i gbe pada si Naijiria, Fawọle ni, ‘‘Ohun to da mi loju ni pe wọn ko to bẹẹ lati gbe Igboho pada si Naijiria. Oju gbogbo agbaye lo n wo wa lori ọrọ Sunday Igboho. Idi ta a fi ni ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn yatọ si atimọle ọlọpaa to wa tẹlẹ ni pe ọgba ẹwọn yẹn la ti ro pe aabo to daju le wa fun un fungba diẹ lo jẹ ka ni ki wọn gbe e lọ sibẹ.

‘‘Ẹru n ba wa pe ẹmi rẹ ko de to ba ṣi wa latimọle tabi ti wọn ba da a silẹ pe ko maa lọ lọjọ Aje ti igbẹjọ rẹ waye. Wọn le yinbọn mọ ọn ki wọn ni awọn ko mọ ẹni to yinbọn pa a. Wọn le ṣe e leṣẹ ki ọrọ naa pada ja si iku, ohunkohun lo le ṣẹlẹ. Ṣẹ ẹ mọ pe awọn eeyan n yinbọn nigba ti wọn gbe e wa si kootu, ki i si i ṣe gbogbo ẹni to wa si kọọtu lo nifẹẹ rẹ, nitori naa la fi gbọdọ ṣọra ṣe. Koda, awọn ẹni ibi le lọọ dena de e ni papakọ ofurufu tabi ni ile ti wọn ba gbe e lọ. Ko si si ile ta a le ni ki wọn gbe e lọ ti aabo to daju maa wa nibẹ. Nitori pe ọgba ẹwọn nikan ni aabo ṣi wa diẹ fun un la fi ni ki wọn gbe e sibẹ.

Nigba to n sọrọ nipa ipo ti Sunday Igboho wa pẹlu bawọn kan ṣe n gbe e kiri pe o tẹ yẹnkẹyẹnkẹ wa si kootu ni, Agbẹjọro Falọla sọ pe oun lọ sọdọ rẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. ‘‘Mo lọ sọdọ rẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, emi ni mo gbe ounjẹ lọ fun un. Emi pẹlu iyawo rẹ la jọ gbe ounjẹ ati aṣọ lọ fun un ni ọjọ Iṣẹgun, bẹẹ ni mo si ri i ni ijẹta, ki gbogbo rẹ too di girigiri lanaa (Ọjọbọ)

Oni (ọjọ Ẹti) lo yẹ ki n tun ri i eyi gan-an ni mo fi pa irun Jimoh to yẹ ki n lọọ ki jẹ ki n le ri awọn iwe to yẹ ki n gba gba, lati le ri i daju pe mo foju kan an. Bakan naa ni mo ti yọju si ọga to wa ni ọgba ẹwọn, mo ṣi tun maa ri i lonii (ọjọ Ẹti), mo ti sọ fun un pe ko ma ri Sunday Igboho gẹgẹ bii ọdaran, mo ni ko tọju rẹ bii ẹni to wa nile ni, ko ma ṣe e bii ọdaran nitori ki i ṣe ọdaran, a kan tọju rẹ sibẹ nitori aabo ẹmi rẹ  ni.

Agbẹjọro to fi orileede France ṣebugbe, to si n ṣiṣẹ aje rẹ nibẹ yii, waa sọ pe ki awọn to ba moju ijọba Buhari kilọ fun un gidigidi, o ṣe pataki ki ijọba naa bọwọ fun ofin. Ko tọ, bẹẹ ni ko si tọna, lati sọ pe wọn fẹẹ ji i gbe, tabi ki wọn fi tipatipa wọ ọ wa si Naijiria. O ni ẹjọ Sunday Igboho ti kuro ni ti ilẹ Naijiria nikan, gbogbo awọn orileede to lagbara lagbaaye lo n woye ibi ti ẹjọ rẹ n lọ.

Leave a Reply