Ẹ wo Adebayọ ti wọn lo lu ale ẹ pa, to tun ba oku ẹ lo pọ

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii, Adebayọ Kingsley, n ṣe awọn alaye kan nipa iku to pa ale rẹ, Rosemary Ifeoma. Alaye naa ko ta leti awọn eeyan, nitori ọmọ oloogbe naa sọ pe Adabayọ lo lagi mọ iya oun lori to fi ku, o si tun mu un gun bii alapa, o ba a sun lẹyin to pa a tan.

Ipinlẹ Edo niṣẹlẹ yii ti waye loṣu keje to pari yii, lopopona Darlington Ogbeifun, nijọba ibilẹ Oredo.

Gbogbo eeyan lo mọ pe ale Ifeoma ni Adebayọ to pe ara ẹ lẹni ọdun mẹtalelogun yii, obinrin naa si bimọ mẹrin fun ọkọ rẹ to ti doloogbe. Eyi to kere ju ninu awọn ọmọ naa nikan lo n gbe pẹlu Ifeoma, ọmọ ọdun mẹtala lọmọ naa, awọn ẹgbọn rẹ ti wa bi yoo ṣe daa fun wọn lọ ni tiwọn.

Ija kan lo ṣẹlẹ laarin Adebayọ ati Ifeoma lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ti obinrin tawọn eeyan mọ si Iya Samuel naa fi ni ki ale oun maa lọ, ko ma wulẹ wa sọdọ oun mọ, oun ko ṣe mọ.

Ọrọ naa dija gidi gẹgẹ bi ọmọ Ifeoma to wa lọdọ ẹ ṣe wi, ọmọ naa ṣalaye pe Kingsley lagi mọ mama oun lori, o si ṣubu lulẹ, bo ṣe dagbere faye niyẹn, nitori ori naa fọ, ẹjẹ si kunlẹ kitikiti.

Ọmọ ọdun mẹtala naa sọ pe Kingsley ti kọkọ kọju ija soun ko too maa ba iya oun ja, o ni o ro pe oun ti ku lo ṣe fi oun silẹ, to lọọ n lu iya oun. Ọmọkunrin naa fi kun un pe lẹyin ti iya oun ti ku silẹ tan ni Kingsley, ọmọ Akoko-Edo, bẹrẹ si i ba a laṣepọ, ko mọ pe oun n ri i.

Nigba to n  ṣalaye ara ẹ, Kingsley sọ pe iṣẹ kan ni ololufẹ oun yii bẹ oun lati ṣe, ṣugbọn awọn ko ri ọrọ naa sọ, o dija, Iya Samuel si le oun jade nile rẹ lalẹ ọjọ naa.

Afurasi yii sọ pe oun jade kuro nile naa loootọ, ṣugbọn oun sọnu loju ọna, boun ṣe tun pada sile rẹ niyẹn. O ni wọn ti ti geeti wọn nigba toun pada debẹ, iyẹn loun ṣe fo fẹnsi wọnu ọgba naa, toun tun wọle lọọ ba ololufẹ oun.

O ni bi Iya Samuel ṣe ri oun ni ko fẹẹ gba koun duro sinu ile naa, ọmọ rẹ naa si doju ija kọ oun pẹlu ọbẹ to mu to fẹẹ fi gun oun, loun ba ti i sẹgbẹẹ kan, bo ṣe fori gba ogiri niyẹn, lo ba ṣubu.

Adebayọ sọ pe Iya Samuel binu, o di oun mu papakoko nitori ọmọ ẹ to ṣubu lulẹ, loun ba ni koun ti iya paapaa danu, bo ṣe ṣubu niyẹn, lo ba fori gbalẹ, bi ẹjẹ ṣe bẹrẹ si i ṣan bala nilẹ niyẹn.

Ọkunrin yii ni oun kọ loun pa Ifeoma, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46). O loun ko lagi mọ ọn lori, nibi tawọn ti n ja lo ti dagbere faye.

O tun loun ko ba oku ẹ sun, irọ lọmọ rẹ n pa mọ oun.

Ṣa, ohun ti oju ẹda ko to, kedere ni loju Oluwa.

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Edo ti lawọn yoo tọpinpin iṣẹlẹ yii delẹ-delẹ, awọn yoo si mọ otito, Kingsley yoo si lọọ jẹjọ rẹ ni kootu bi ijọba ba ṣe kọwe rẹ.

Leave a Reply