Wọn na baba to fẹẹ ba iyawo ọmọ ẹ lo pọ lẹgba nita gbangba

Ọkunrin ti wọn n na lẹgba yii ki i ṣe ọmọ kekere, agbalagba ẹni ọdun mẹtalelọgọta (63) ni. Ẹṣẹ to ṣẹ ti wọn fi n na an ni gbagede bayii ni pe o gbiyanju lati ba iyawo ọmọ rẹ lo pọ, niyẹn ba fẹjọ rẹ sun awọn agbaagba ile, bi wọn ṣe da sẹria ti wọn maa n da fẹni to ba ṣe bẹẹ fun baba yii torukọ rẹ n jẹ Moses Oluka niyẹn.

Orilẹ-ede Uganda niṣẹlẹ yii ti waye, ni abule kan ti wọn n pe ni Akero, ni ẹkun Bukedea. Ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni ojo ẹsin Moses to ṣu bẹrẹ si i rọ, nigba ti wọn bo o lẹgba mẹwaa nidii, ti wọn gba akọ ewurẹ kan lọwọ rẹ, to tun fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un owo ilu wọn gbara.

Gẹgẹ bi olori ile awọn baba yii ṣe wi, iyẹn baba kan torukọ tiẹ n jẹ Martine Okwii, o ni eyi kọ ni igba akọkọ ti Moses yoo gbiyanju iwa yii. O ni awọn iyawo ọmọ rẹ kan jẹwọ fawọn pe baba ti wọle waa ba awọn ri, to si mu nnkan jẹ lara awọn, ko kan ṣee sọ sita ni.

Iyawo to tu aṣiri ẹ yii ni wọn n pe ni Jessica Alupo, oun lo sọ fun ọkọ ẹ to jẹ ọmọ baba yii pe niṣe ni baba rẹ n nawọ ifẹ soun o, baba fẹẹ ṣe ohun ti ọmọ rẹ n ṣe lara oun.

Samuel lọkọ Jessica n jẹ, bo ti gbọ ọrọ naa ni ibinu rẹ ru soke, ko si duro rara toun atiyawo naa fi lọọ fẹjọ baba rẹ sun olori ile.

Awọn agbaagba ṣewadii, wọn ri i pe bẹẹ lo ri loootọ. Wọn pe Moses naa ko waa ṣalaye, ko ri kinni kan sọ, ni wọn ba ni yoo jiya ti ẹni to ba dan iru eyi wo lọdọ awọn maa n jẹ.

Ijiya naa ni pe wọn yoo da oniṣina naa dubulẹ loju gbogbo ara abule, wọn yoo na an ni bilala mẹwaa, yoo sanwo itanran, wọn yoo si tun gba akọ ewurẹ kan lọwọ rẹ pẹlu. Ohun ti wọn ṣe fun Moses Oluka to n ṣere egele laarin awọn iyawo awọn ọmọ rẹ naa niyẹn.

Leave a Reply