Ọmọọba ti ọlọpaa kogberegbe yinbọn lu l’Oṣogbo ti ku o

Florence Babaṣọla

Ọmọọba Saheed Ọlabomi, ọmọkunrin ti ọlọpaa kogberegbe kan yinbọn lu lagbegbe Islahudeen, niluu Oṣogbo, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja, ti jade laye.

Ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe Saheed, ẹni to jẹ ọmọ ẹgbọn Aragbiji ti ilu Iragbiji, Ọba Abdulrasheed Ayọtunde Ọlabomi, mi eemi ikẹyin.

Ọmọ bibi ilu Iragbiji ni Saheed, ilu Oṣogbo lo n gbe, o ni iyawo kan, o si bimọ meji. Ileewe gbogboniṣe ipinlẹ Kwara lo ti kẹkọ pari, ko too bẹrẹ ka-ra-ka-ta niluu Oṣogbo. Ọmọ ọdun mejidinlọgbọn ni ko too pade iku ojiji rẹ nirọlẹ ọjọ naa.

Lasiko ti awọn ọlọpaa kogberegbe naa n kọja ninu sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ lagbegbe ọhun ni ọkan lara wọn yinbọn soke, to si ba Saheed loju.

Latigba naa lo ti wa nileewosan UNIOSUN pẹlu ẹnjinni ti wọn fi n mi lẹnu rẹ, ṣugbọn ti ọlọjọ de lalẹỌjọbọ.

Bo tilẹ jẹ pe Alukooro ọlọpaa l’Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe igbẹjọ ti bẹrẹ lori ọrọ ọlọpaa naa, sibẹ, ohun ti awọn mọlẹbi Saheed n fẹ ni igbẹjọ itagbangba ati idajọ ododo.

Leave a Reply