Ẹ wo Abiọdun ati Adeleke ti wọn ja Kọpa John lole n’Ikẹja

Faith Adebọla, Eko

Ẹni ogoji ọdun ni Ọgbẹni Abiọdun Idowu yii, oun ati ọrẹ ẹ, Adeleke Adekunle, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni wọn sọ ole jija loju popo di iṣẹ gidi, ṣugbọn ori ta ko wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, bi wọn ṣe ja agunbanirọ John Ọlakunle lole foonu ẹ tan lọwọ to wọn.

Gẹgẹ bi atẹjade kan lati ọfiisi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣe sọ, CSP Olumuyiwa Adejọbi ṣalaye pe jija foonu ati owo gba lawọn jagunlabi ọdaran yii mu niṣẹ, o ni agbegbe tero pọ si ni Opopona Ọbafẹmi Awolọwọ, to fi mọ ọja igbalode Computer Village, ni wọn ti n ṣọṣẹ lojoojumọ.

Lọjọ tọwọ palaba wọn segi yii, agunbanirọ to n ṣin ijọba lagbegbe Ikẹja, l’Ekoo, Kọpa John, lo ko si wọn lọwọ, ni wọn ba yọ ibọn ati ọbẹ aṣooro si i nigba tiyẹn n dari re’le, wọn si fipa gba foonu Samsung Galaxy A20 to wa lọwọ ẹ.

Bi wọn ṣe ja foonu ọkunrin naa gba tan ti wọn bẹsẹ wọn sọrọ ni John figbe ta, awọn ti wọn si ri wọn ṣugbọn ti wọn ko mọ pe iru iṣẹ buruku bẹẹ ni wọn n ṣe lọjọ naa lo ke sawọn ọlọpaa ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squard) to wa nitosi, wọn si bẹrẹ si i le wọn, titi ti wọn fi ri wọn mu.

Nigba ti wọn de teṣan ọlọpaa, Abiọdun jẹwọ pe ọmọ bibi Ṣagamu, lagbegbe Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, loun, ṣugbọn Ojule kẹta, Opopona Sẹgilọla, l’Agege, nipinlẹ Eko, loun n gbe.

Adeleke Adekunle ni ọmọ Ila-Ọrangun, nipinlẹ Ọṣun, loun ni toun, Ojule keje, Opopona Ararọmi, ni Kọla, Alagbado, nipinlẹ Eko, lo pe adirẹsi tiẹ l’Ekoo.

Awọn mejeeji jẹwọ fawọn ọlọpaa pe o ti pẹ diẹ tawọn ti n jale n’Ikẹja, ṣugbọn foonu ati owo nikan lawọn maa n ji, wọn si tun juwe awọn ti wọn n ta a fun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn afurasi ọdaran mejeeji si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ki wọn le tubọ ṣalaye ara wọn daadaa fawọn agbofinro to n ṣewadii, lẹyin naa ni wọn maa fi wọn ṣọwọ sile-ẹjọ, ki wọn le fimu kata ofin.

Leave a Reply