Ọkan ninu awọn ibeji Ajogbajesu olorin ti ku o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Owurọ kutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu keje, ọdun 2021, ni iku ṣoro nile awọn ibeji Ajogbajesu ti wọn maa n kọrin ẹmi, ọkan ninu wọn tawọn eeyan mọ si Tọpẹ, lo ku lojiji.

Ṣe o ti to ọjọ mẹta tawọn eeyan tilẹ ti gbọ nipa awọn ibeji Ajogbajesu yii gbẹyin, asiko ti Ọgbeni Gbenga Adewusi n gbe wọn jade lokiki wọn jade daadaa.

Ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe yatọ si pe awọn eeyan ko fi bẹẹ gbọ nipa wọn mọ, wọn ni o pẹ ti ara Tọpẹ Ajogbajesu ko ti ya ni tiẹ, to jẹ wọn n gbe e kiri fun itọju ni.

Ẹnikan to sun mọ wọn daadaa tilẹ sọ pe oun ri Tọpẹ yii pẹlu mama wọn lori oke adura Agelu laipẹ yii, nibi ti wọn ti lọọ gbadura lori aarẹ to n ṣe ọkunrin olorin ẹmi naa.

Afi bo ṣe di lọjọ Jimọh yii ti ọkunrin naa fi ikeji rẹ silẹ, to gba ajule ọrun lọ. Latigba ti awọn ololufẹ wọn ti gbọ nipa iku to pa ọkan ninu awọn ibeji yii ni wọn ti n ṣedaro wọn.

Leave a Reply