Kafaya fibinu lu ọmọ ẹ pa l’Ogijo, o ni irinkurin ẹ ti pọ ju

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Aaya loun fẹẹ tun oju ọmọ oun ṣe ni, afigba to kọwọ bọ ọ, loju ba fọ ọ. Eyi ni akawe tawọn eeyan n ṣe lori ọrọ obinrin kan, Kafayat Lawal, ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) to ni awọn ọmọ oun obinrin mejeeji n rin irinkurin, to fẹẹ ba wọn wi, to ti wọn mọ yara, to si bẹrẹ si i fi ekufọ igo da sẹria fun wọn, eyi to fa iku ọkan lara awọn ọmọ naa.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje, niṣẹlẹ yii waye. Awọn eeyan kan ni wọn ta DPO teṣan Ogijo lolobo, pe Kafaya ti lu ọmọ ẹ to n jẹ Ayọmide Adekọya pa o.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun(17) ni Ayọmide to ku yii, ẹgbọn rẹ, Blessing Adekọya, si jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun (19).

Nigba tawọn ọlọpaa mu Kafaya de teṣan nitori iku ọmọ rẹ, o ṣalaye pe oun ko mọ-ọn-mọ pa ọmọ oun.

Obinrin naa sọ pe ọdun kẹsan-an ree ti oun pẹlu baba awọn ọmọ naa ko ti fẹ ara awọn mọ, to jẹ oun nikan loun n tọju wọn titi ti wọn fi di ọlọmọge bayii.

Iya yii tẹsiwaju pe lọjọ ọdun Ileya to kọja yii, awọn ọmọ oun meji yii gbe ọdun jade lọ. Kaka ki wọn si pada wale lasiko, o ni wọn ko tiẹ wulẹ de lọjọ naa ni, niṣe ni wọn sun ita. Eyi bi oun ninu pupọ, oun si fẹẹ lu wọn lọjọ keji ti wọn de, ṣugbọn awọn eeyan to wa nitosi ba wọn bẹbẹ, oun si fi wọn silẹ, oun ko lu wọn mọ.

Afi bawọn ọmọge meji naa ṣe tun jade lọ lọjọ keji, ni wọn ko ba tun sun ile, ọjọ kẹta ni wọn too de.

Eyi ni Kafaya sọ pe o mu inu bi oun ju, toun fi ti wọn mọ yara, toun si bẹrẹ si i lu wọn, toun tun yọ ẹkufọ igo si wọn.

   Igo naa gun Blessing to jẹ agba lọwọ, ṣugbọn aya lo ti gun Ayọmide ni tiẹ. Wọn sare gbe ọmọ naa lọ sọsibitu nigba ti oju iya wọn walẹ tan, ṣugbọn nibi ti Ayọmide ti n gbatọju lo ti dakẹ.

Bi iya wọn ṣe di ero teṣan ọlọpaa niyẹn.

CP Edward Ajogun, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, paṣẹ pe ki wọn gbe Kafaya lọ sẹka awọn apaayan, ki wọn maa fọrọ wa a lẹnu wo nibẹ titi ti yoo fi dele-ẹjọ.

 

Leave a Reply