Nitori irin to ji ko, Yisa dero kootu l’Ekiti

Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

Wọn ti foju afurasi ole kan, Yisa Awesu, han ni kootu Majisreeti Ado-Ekiti, fun pe o ji irin ikọle ti owo ẹ to ẹgbẹrun lọna aadọta naira ko nibi ile kan ti wọn n kọ lọwọ.

Ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) ni Yisa tọwọ ba yii. Agbefọba Oriyọmi Akinwale, sọ fun kootu pe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, ọdun 2021, ni olujẹjọ huwa ole jija, ni deede agogo mẹfa irọlẹ, laduugbo Irona, Ado-Ekiti.

Akinwale ṣalaye pe irin mejilelọgun ni Yisa ji ko nile ti wọn n kọ lọwọ naa, awọn to si ni irin naa ni Ọlaṣeni Ọdunayọ ati Ọladimeji Victoria.

Ẹsun yii lodi ninu iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Ekiti, eyi ti wọn ṣe lọdun 2012. Ṣugbọn Yisa ti wọn fẹsun kan loun ko jẹbi.

Adajọ M.O Faola to gbọ ẹjọ naa faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira ati oniduuro kan niye kan naa. Igbẹjọ mi-in di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Leave a Reply