Idibo wọọdu l‘Ọṣun: Awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC fẹhonu han, wọn ni Oyetọla ko le yan le awọn lori

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe lawọn ọdọ kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ọṣun, fọn soju titi nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu keje yii, lati fẹhonu han si ohun ti wọn pe ni ọgbọn alumọkọrọyin ti Gomina Oyetọla ati alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Gboyega Famọdun, n lo lati ma ṣe jẹ ki eto idibo wọọdu waye lọla.

Lati bii oṣu kan ni igbimọ afun-n-ṣọ apapọ ẹgbẹ naa lorileede yii ti kede ọjọ Abamẹta,       Satide, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, gẹgẹ bii ọjọ ti idibo wọọdu yoo waye, latigba naa ni awọn ti wọn jẹ ‘The Osun Progressives’ ti n fẹsun kan awọn Ileri Oluwa pe ṣe ni wọn fẹẹ yan le gbogbo ọmọ ẹgbẹ lọwọ.

Lọsẹ to kọja ni awọn TOP kegbajare si awọn alakooso ẹgbẹ lorileede yii pe Gomina Oyetọla ko gbogbo fọọmu ti wọn ko ranṣẹ lati Abuja sabẹ, ti wọn ko si jẹ ki awọn miiran lanfaani si fọọmu ọhun ju awọn ti wọn n pe ara wọn ni Ileri Oluwa lọ.

Nigba ti ọrọ ti di bayii lawọn naa mori le Abuja lati gba fọọmu wọn, eleyii ti wọn ni o fa a ti gomina tun fi ko awọn ti Abuja ran wa lati ṣakoso idibo ọjọ Ẹti naa pamọ, ti wọn ko si jẹ ki wọn lọ si sẹkiteriati ẹgbẹ to wa ni Ogo-Oluwa, l’Oṣogbo.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn olufẹhonu han naa, Rasheed Raji, ṣe wi, “Iwa to le tu ẹgbẹ ni Gomina Oyetọla ati Ọmọọba Famọdun n hu lọwọlọwọ bayii, inu otẹẹli ni wọn ko awọn ti ẹgbẹ ran wa lati ta fọọmu fun wa si, wọn ko jẹ ka lanfaani si fọọmu bo tilẹ jẹ pe ogunlọgọ awọn eeyan wa ni wọn ti sanwo fọọmu tipẹ.

“A ko mọ idi ti idibo fi n ba wọn lẹru, a sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ka dibo yan awọn to ba wu wa, awọn ti wọn yoo ṣeto idibo lọla tun ti de, wọn tun ti ti wọn mọ inu ile-ijọba dipo sẹkiteriaati to yẹ ki wọn wa.

“A n fi asiko yii ke si igbimọ ti Mai Mala Buni n dari lati da si wahala to n ṣẹlẹ lọwọ bayii nipinlẹ Ọṣun ko too ṣe akoba to pọ fun ẹgbẹ wa.”

Bakan naa ni Arabinrin Ọpẹyẹmi Awotipẹ bu ẹnu atẹ lu iwa ko sẹni ti yoo mu mi ti alaga ẹgbẹ naa l’Ọṣun, Ọmọọba Famọdun n hu. O ni ẹgbẹ alaafia ni wọn mọ ẹgbẹ oṣelu APC si tẹlẹ, ṣugbọn iwa ti alaga naa n hu bayii n kọ awọn lominu.

O ṣalaye pe wọn ti pinnu lati maa na ẹnikẹni to ba bọ sipo lati dibo lọla nitori ṣe ni wọn fẹẹ maa buwọ lu orukọ awọn ti wọn ri bii oloootọ si wọn, ti wọn yoo maa lo lati dari ẹgbẹ bo ṣe wu wọn.

Adetipẹ waa ke si awọn alakooso ẹgbẹ lati ke si awọn to n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ naa l’Ọṣun pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ’ṣọ, ki awọn oṣiṣẹ alaabo si ṣiṣẹ wọn lọna to ba ofin orileede yii mu.

Leave a Reply