Ile-ẹjọ ni ki Lai Muhammed atawọn alatilẹyin rẹ lọọ ti ile ẹgbẹ ti wọn kọ pa ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti paṣe pe ki Minisita fun ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Muhammed, ati awọn alatilẹyin rẹ lọọ ti ile ẹgbẹ wọn tuntun ti wọn kọ si Opopona Yahaya Madawaki, GRA, niluu Ilọrin pa latari pe wọn kọ ile ẹgbẹ wọn tuntun ọhun lọna ti ko bofin mu.

Tẹ o ba gbagbe, lati bii oṣu meloo kan sẹyin ni gbọn mi si i, omi o to o ti n waye laarin awọn alatilẹyin Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, atawọn alatilẹyin Lai Muhammed, eyi lo mu ki Lai Muhammed atawọn alatilẹyin rẹ lọọ kọ ile ẹgbẹ tiwọn lọtọ, wọn ni kaka ki kiniun sakapo Ẹkun, ki onikaluku ṣọdẹ rẹ lọtọọtọ.

Onidaajọ Ẹ.B Mohammed ti waa pasẹ pe ki wọn lọ ti ile ẹgbẹ naa pa, tori pe wọn kọ ọ lọna ti ko tọ, ki wọn si maa lo ile ẹgbẹ APC kan ṣoṣo ti ẹgbẹ ọhun ni nipinlẹ Kwara.

 

Leave a Reply