Ọwọ ba mẹta ninu awọn to n ṣẹgbẹ okunkun l’Abẹokuta, olori wọn fara gbọta lọ

Gbenga Amos, Abeokuta

Awọn afurasi ọdaran to n ṣẹgbẹ okunkun l’Abẹokuta ti pinnu p’awọn o ni i wọn ọn kun, ileeṣẹ ọlọpaa naa si ti yari p’awọn o ni i gba a laabọ. Fun bii ọgbọn iṣẹju ni iro ibọn fi n dun ni kọṣẹkọṣẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje yii, nigba tawọn ọlọpaa lọọ ka awọn ẹlẹgbẹkẹgbẹ ọhun mọ’bi ti wọn ti n ṣepade aburu wọn, wọn yinbọn mọ wọn, awọn naa fibọn fesi, asẹyinwa-asẹyinbọ, ọwọ ba mẹta ninu wọn, ọpọ ninu awọn to sa lọ, titi kan olori wọn, lo fara gbọta ibọn.

Orukọ awọn mẹta tọwọ ba ọhun ni, Jonathan Oṣikanlu, Kọla Bọlugbẹ ati Jimọh Aliu ti inagijẹ rẹ n jẹ Alaayan.

Gẹgẹ bi atẹjade ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi lede lori iṣẹlẹ yii, o ni olobo kan lo ta ikọ SWAT (Special Weapon and Tactical Team) ileeṣẹ ọlọpaa, pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti kora jọ sinu igbo ṣuuru kan to wa lọna Ogun redio, lagbegbe Mile 2, ni Lafẹnwa, Abẹokuta. Wọn ni olori awọn ẹlẹgbẹ okunkun kan tawọn ọlọpaa ti n wa tipẹ, Ben lorukọ ti wọn mọ ọn si, oun ni wọn lo ko ipade naa jọ lati jiroro akọlu mi-in ti wọn fẹẹ ṣe. Wọn lo ti to eeyan bii marun-un ti Ben yii mọ nipa iku wọn latẹyinwa, ti wọn si n tori ẹ wa a loju mejeeji.

Kia ti wọn gbọ ti ipade yii ni lawọn ọlọpaa ẹka Lafẹnwa ati ti Ilupeju ti lọọ ka awọn afurasi naa mọ inu igbo ti wọn wa, ṣugbọn kaka ki wọn tuuba, o jọ pe awọn onipade ọran yii ti mura silẹ de awọn ọlọpaa, niṣe ni wọn yinbọn mọ wọn, lawọn ọlọpaa naa ba fibọn fesi, awọn araalu si bẹrẹ si i sa kijokijo, ṣugbọn ọwọ awọn ọlọpaa ro ju tiwọn lọ.

Nigbẹyin, wọn ri awọn mẹta mu, ibọn ba Ben, ṣugbọn o raaye sa lọ, awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa ba ọkọ ọlọpaa kan jẹ, wọn fọ gilaasi ẹ, bẹẹ lawọn ọlọpaa naa ri ọkọ ayọkẹlẹ Lexus 330 ti ko ni nọmba kan tawọn ẹlẹgbẹ ọkunkun ọhun gbe wa, gba nidii wọn.

Ṣa, awọn mẹta yii ti wa lahaamọ, lolu-ileeṣẹ ọlọpaa Ogun to wa l’Eleweeran, wọn ti wa lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ to n ṣiṣẹ iwadii, lati le tọpasẹ awọn to sa lọ, atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn wọnyi sile-ẹjọ ti iwadii ba ti pari, bẹẹ lo leri pe arọni o wale, onikoyi o sinmi ogun, ni laarin oun atawọn ẹlẹgbẹkẹgbẹ yii, afi ti wọn ba tuuba, ti wọn si jawọ.

Leave a Reply