Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pẹlu bo ṣe jẹ pe owo burẹdi ti goke si i kaakiri ni Naijiria bayii, awọn ti wọn n ṣe ohun jijẹ naa ti sọ pe ko tun si igba tawọn ko tun ni i fi kun owo rẹ si i, nitori fulawa tawọn fi n ṣe e ko yee gbẹnu soke, niṣe ni owo rẹ n fojoojumọ le si i.
Aarẹ awọn to n ṣe burẹdi ni Naijiria, Daud Suleiman lo sọ eyi di mimọ.
O ni loṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ẹgbẹrun mẹwaa ati ọọdunrun naira (1,300) ni apo iyẹfun fulawa kan. Ṣugbọn lati ọsẹ to kọja yii lọ, ẹgbẹrun lọna ogun naira (20,000) ni wọn n ta apo kan bayii.
Lori ohun to n fa a eyi, o ni owo dọla lo n fa a. Bi owo dọla ba ti lọ soke, niṣe lawọn to n ṣe iyẹfun fulawa yii yoo fowo kun iye ti wọn n ta a. Bẹẹ, wọn ni bi wọn ṣe le ṣetọju fulawa ti wọn ti ṣe silẹ lasiko ti dọla ko ti i wọn, ti ko fi ni i bajẹ, ṣugbọn wọn ko ni i ṣe bẹẹ. Wọn yoo gbe owo le e ni, eyi yoo si ṣakoba fawọn nigba tawọn ba n fowo nla ra a. Iyẹn lo fi jẹ ko si ọna mi-in ju kawọn naa fowo le burẹdi nigba to ba delẹ lọ.
Aarẹ awọn oniburẹdi yii sọ pe laarin oṣu kan,awọn onifulawa le fi owo kun un lẹẹmẹta.
Ṣugbọn ki i ṣe bi owo fulawa ṣe wọn ni awọn orilẹ-ede yooku bii Gambia ati Bẹnnẹ ree, gẹgẹ bi Daud ṣe wi.
O ni awọn onifulawa n mọ-ọn-mọ fi owo le ti Naijiria yii ni. Bakan naa lo ni iyẹfun fulawa awọn orilẹ-ede adulawọ yooku daa ju ti Naijiria lọ.
Ohun to tiẹ mu ọrọ naa toju suuyan gẹgẹ bo ṣe wi ni pe awọn orilẹ-ede yooku yii ki i ṣe fulawa lọdọ wọn, wọn n ko o wọle lati ilu mi-in ni. Ṣugbọn ni Naijiria nibi, a ni ileeṣẹ fulawa daadaa, ṣugbọn tiwa lo tun wọn ju.
“Awọn ti wọn n ṣe fulawa lọga awa ta a n ṣe burẹdi, a ko ri ohunkohun ṣe fun wọn lati gba ara wa silẹ rara. O yẹ ka jẹ ọrẹ ara wa ni, ṣugbọn awa o lagbara lori wọn” Bẹẹ ni Aarẹ awọn oniburẹdi naa sọ.
Ṣugbọn awọn araalu lo n jiya owo-ori burẹdi to n goke yii, ọpọ eeyan lo si n sọ pe ounjẹ mẹkunnu lo yẹ ki burẹdi jẹ, nigba ti ki i ṣe ounjẹ inu agolo bii tawọn oyinbo, to si jẹ loju wa nibi naa ni wọn ti n ṣe e.
Bo ṣe waa n di ohun ti owo kekere ko fẹẹ ṣee ra mọ yii, ọpọ eeyan lo n sọ pe ọrọ burẹdi to n fojoojumọ wọn yii ti su awọn.