Ọwọ tẹ Desmond atọrẹ ẹ, ọmọ ọdun mẹjọ ni wọn ji gbe n’Ipaja

Faith Adebọla, Eko

Ọrẹ ki i ya ọrẹ lawọn mejeeji, afaimọ si lọrẹ wọn ko ni i gbe wọn de ọgba ẹwọn, tori ahamọ ọlọpaa ni Desmond ati ọrẹ ẹ, Egwuonwu, wa bayii, ori  lo ko ọmọ ọdun mẹjọ kan, Daniel Chukwudi, yọ ti wọn ji gbe yọ lọwọ wọn, ọpẹlọpẹ awọn agbofinro ipinlẹ Eko,

Ẹni ọdun mọkanlelogun pere ni Desmond Ikechukwu Okafor, oun gan-an ni wọn lo gan ọmọ ọhun lapa, ekeji ẹ, Egwuonwu Gift Iyke, si jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Adekunle Ajiṣebutu, to fi ọrọ yii to ALAROYE leti lori ikanni Wasaapu ẹ sọ pe ọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun 2021 ni iṣẹlẹ naa waye.

Wọn ni ọrẹ timọtimọ ni Desmond pẹlu awọn obi ọmọ to ji gbe yii, o maa n lọọ ṣere nile wọn daadaa, lagbegbe Aboru, n’Ipaja, nipinlẹ Eko, ti wọn n gbe.

Lọjọ tiṣẹlẹ naa waye, niṣe ni Desmond ṣe bii ẹni to fẹẹ sin ọmọ naa dele awọn obi ẹ, ko si sẹni to fura pe erokero ti wa lọkan ẹ, afi bi wọn ṣe de kọrọ kan, lo ba ki ọmọ naa mọlẹ, o gbe e si mọto, o tan an pe oun fẹẹ ra nnkan fun un, loun ati Iyke ba wa ọmọ ọlọmọ lọ si ile ile kan ti ko seeyan nibẹ ni Ajangbadi, lọna Olodi Apapa.

Ọjọ mẹfa ni wọn fi bo ọmọ naa mọle, wọn o jẹ ko yọju sita, wọn ni niṣe ni wọn da aṣọ dudu bo o lori mọlẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn n fun un lounjẹ ati omi, ko ma baa ku.

Ẹyin ti wọn dọhun ni ẹnikan pe baba ọmọ naa lori foonu pe akata awọn ni ọmọ ẹ to sọnu wa, ko lọọ wa miliọnu meji aabọ naira wa ni kiakia to ba ṣi fẹẹ ri ọmọ rẹ laaye, wakati mẹrinlelogun pere lawọn fun un.

Ṣugbọn awọn obi ọmọ ti fọrọ naa to awọn ọtẹlẹmuyẹ leti tẹlẹ, iwadii ati imọ ijinlẹ lo tu aṣiri ibi ti wọn ti n lo foonu ti wọn fi n pe ọhun, ibẹ naa lawọn agbofinro si ka wọn mọ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn.

Ajiṣebutu ni awọn ṣi n ba iwadii lọ lati mọ awọn amookunṣika ti wọn tun lọwọ ninu iwakiwa yii, o ni gbogbo wọn ni wọn maa kawọ pọnyin rojọ laipẹ.

Leave a Reply