Ọwọ EFCC tẹ obinrin kan pẹlu kaadi idibo rẹpẹtẹ ni Kaduna

Monisọla Saka

Ọwọ awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC, ti tẹ obinrin kan, Maryam Alhaji, laaarọ kutukutu ọjọ Abamẹta Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, pẹlu kaadi idibo mejidinlogun, lagbegbe Badarwa, Kaduna, nipinlẹ Kaduna.

Obinrin ọhun, Maryam Mamman Alhaji, ti wọn lo jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to n le waju lorilẹ-ede yii, tun ni iwe to ni bii oju ewe mẹtadinlogun kan lọwọ, eyi to kun fun orukọ awọn oludibo, nọmba ati orukọ banki wọn, to fi mọ nọmba ẹrọ ibanisọrọ wọn, gẹgẹ bi orukọ wọn ṣe wa ninu akọsilẹ ajọ eleto idibo agbegbe Badarwa ati Malali, Wọọdu kin-in-ni ati ikẹjọ, ijọba ibilẹ Ariwa Kaduna, nipinlẹ naa.

Awọn ajọ yii ni obinrin ọhun ko si panpẹ awọn lẹyin tawọn ti wọn n ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ laarin awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC dọgbọn ṣe bii ẹni to fẹẹ ta kaadi idibo wọn, lai bikita iyekiye ti wọn ba fẹ ra a.

Ṣaa, obinrin naa ti wa ni ahamọ awọn ajọ EFCC, ẹka ti ipinlẹ Kaduna bayii, nibi to ti n kawọ pọnyin rojọ, pẹlu erongba pe yoo darukọ awọn eeyan ẹ yooku to sọ pe awọn jọ n ra ibo lọwọ awọn eeyan, tawọn yoo si fi ẹrọ POS sanwo fun wọn, tabi kawọn fi ṣọwọ si banki koowa wọn.

Bakan naa ni EFCC tun fi panpẹ ofin gbe ọkunrin kan ti wọn lo n ra ibo pẹlu owo to to ẹgbẹrun lọna igba Naira, o din mẹfa (194,000), nibudo idibo Gidan Zakka, agbegbe Goron Dutse, nijọba ibilẹ Kano Municipal, nipinlẹ Kano. Bẹẹ ni wọn tun nawọ gan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ti wọn maa n wa nibudo idibo, awọn wọnyi ni wọn sọ pe wọn n sanwo si banki awọn ti wọn ba ra ibo lọwọ wọn niluu Abuja.

Leave a Reply