Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Owo ni Abilekọ Muslimah Babaita, to jẹ olukọ nileewe Government Day Secondary School Alore, Ilọrin, lọọ gba ni ileefowopamọ Access, lagbegbe Surulere, niluu Ilọrin, to fi dawati lẹyin ọjọ kẹfa ni wọn ri i niluu Saki, nipinlẹ Ọyọ, ti ko le sọrọ mọ.
ALAROYE, gbọ pe Abilekọ Muslimah Babaita, jade nile ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-ni-in, ọdun yii, to lọọ gbowo ni ileefowopamọ Access to wa ni agbegbe Surulere, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti wọn ko si ri i mọ. Gbogbo igbiyanju awọn mọlẹbi lati mọ ibi to wa lo ja si pabo. Wọn pe ẹrọ ibanisọrọ titi ko lọ, ṣugbọn lẹyin ọjọ keje ni wọn gburoo rẹ niluu Saki, nipinlẹ Ọyọ.
Ni bayii, Abilekọ Muslimah, ti dari wale, o si ti dara pọ mọ awọn mọlẹbi rẹ, ṣugbọn ko le sọrọ mọ, koda ko da mọlẹbi kankan mọ mọ, o kan n wo bọ ọ ni, wọn ti waa gbe e lọ si ileewosan alaadani kan ti wọn ko darukọ niluu Ilọrin fun itọju to peye.