Stephen Ajagbe, Ilọrin
O kere tan, awọn afurasi ọgọrun-un kan ati mẹrinlelogoji lọwọ ọlọpaa ti tẹ niluu Ilọrin pe wọn ji ẹru ijọba ati tawọn ile itaja nla ko lasiko ifẹhonu han ta ko SARS lọsẹ to kọja.
Nigba to n ṣafihan wọn pẹlu awọn ẹru ti wọn ji ko ni olu ileeṣẹ ọlọpaa n’Ilọrin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Ọga ọlọpaa, Kayọde Ẹgbẹtokun, ni awọn ba ara ẹru ti wọn ji lakata awọn afurasi naa.
Ẹgbẹtokun ṣeleri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tẹsiwaju lati tọpinpin gbogbo awọn to ji nnkan ko, awọn yoo si gba awọn ẹru naa pada lọwọ wọn.
O ni gbogbo kọrọ kọndu ilu Ilọrin ati ipinlẹ Kwara lawọn yoo de lati gbe awọn to ji ẹru ti ki i ṣe tiwọn ko.
O ni iṣẹ ọhun lawọn yoo jọ ṣe pẹlu awọn agbofinro yooku lati ri i pe gbogbo awọn ọdaran naa lọwọ tẹ.
Ọga ọlọpaa naa gba gbogbo awọn to ba ni ẹru ti wọn ji lakata wọn lati jọwọ rẹ wọrọọwọ ko too di pe pampẹ ofin ba wọn.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣiju aanu wo gbogbo awọn to ba finu-findọ yọnda awọn ẹru naa.